0:00
0:00

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (Allāhu) máa sọ iṣẹ́ wọn dòfò.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n tún gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) Muhammad, òhun sì ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (Allāhu) máa pa àwọn (iṣẹ́) aburú wọn rẹ́, Ó sì máa ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀ wọn sí dáadáa.
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ tẹ̀lé irọ́. Àti pé dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ tẹ̀lé òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi àpèjúwe wọn lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn.
Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi borí wọn. (Tí ẹ bá ṣẹ́gun) kí ẹ dè wọ́n nígbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí (okùnfà) ogun ẹ̀sìn yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀. Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun jíjà lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú ogun ẹ̀sìn, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfò.
Ó máa tọ́ wọn sọ́nà. Ó sì máa tún ọ̀rọ̀ wọn ṣe sí dáadáa.
Ó máa fi wọ́n wọ inú Ọ gbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n.
____________________
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fi Ọ gbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀ mọ̀ wá pẹ̀lú oríkì kíkún àti àkàwé t’ó lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ọkàn wa fi ń jẹ̀rankàn rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa fi ṣíjú àánú Rẹ̀ wò wá lọ́jọ́ Àjíǹde.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn yín lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, ègbé ni fún wọn. (Allāhu) sì máa ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, (Allāhu) sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Allāhu pa wọ́n rẹ́. Irú rẹ̀ tún wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn.
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọ gbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn ń gbádùn, wọ́n sì ń jẹ (kiri) gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran-ọ̀sìn ṣe ń jẹ (kiri). Iná sì ni ibùgbé fún wọn.
Mélòó mélòó nínú àwọn (ará) ìlú tí ó lágbára ju (ará) ìlú rẹ, tí ó lé ọ jáde, tí A sì ti pa wọ́n rẹ́. Kò sì sí alárànṣe kan fún wọn.
Ǹjẹ́ ẹni tí ó wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, ṣé ó dà bí ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn?
Àpèjúwe Ọ gbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (nìyí): àwọn omi odò wà nínú rẹ̀ tí kò níí yí padà àti àwọn odò wàrà tí adùn rẹ̀ kò níí yí padà àti àwọn odò ọtí dídùn fún àwọn t’ó máa mu ún àti àwọn odò oyin mímọ́. Àwọn onírúurú èso wà fún wọn nínú rẹ̀ àti àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (Ṣé ẹni tí ó wà nínú Ọ gbà Ìdẹ̀ra yìí) dà bí olùṣegbére nínú Iná bí, tí wọ́n ń fún wọn ní omi gbígbóná mu, tí ó sì máa já àwọn ìfun wọn pútupùtu?
Ó wà nínú wọn, ẹni tí ó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ títí di ìgbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ tán, wọn yó sì wí fún àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pé: "Kí l’ó sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀ kan ná?" Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti dí ọkàn wọn pa. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn.
Àwọn t’ó sì tẹ̀lé ìmọ̀nà, (Allāhu) ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn. Ó sì máa fún wọn ní ìbẹ̀rù wọn (nínú Allāhu).
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà, tí ó máa dé bá wọn ní òjijì? Àwọn àmì rẹ̀ kúkú ti dé. Nítorí náà, báwo ni ìrántí (yó ṣe wúlò fún) wọ́n nígbà tí ó bá dé bá wọn?
Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùsinmi yín.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Gọ̄fir; 40: 55.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ń sọ pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ sūrah kan kalẹ̀?" Nígbà tí wọ́n bá sọ sūrah aláìnípọ́n-na kalẹ̀, tí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ìjà ogun ẹ̀sìn nínú rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa wò ọ́ ní wíwò bí ẹni pé wọ́n ti dákú lọ pọnrangandan. Ohun tí ó sì dára jùlọ fún wọn
____________________
Wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3: 7.
ni ìtẹ̀lé àṣẹ (Allāhu) àti (sísọ) ọ̀rọ̀ rere. Nígbà tí ogun ẹ̀sìn sì ti di dandan, wọn ìbá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ìbá dára jùlọ fún wọn.
Ǹjẹ́ kò súnmọ́ tí ẹ̀yin (aláìsàn ọkàn wọ̀nyí) bá dé’pò àṣẹ, pé ẹ ò níí ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti pé ẹ ò níí já okùn-ìbí yín?
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn.
Ṣé wọn kò níí ronú nípa al-Ƙur’ān ni tàbí àwọn àgádágodo ti wà lórí ọkàn wọn ni?
Dájúdájú àwọn t’ó pẹ̀yìn dà (sí ’Islām) lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, Èṣù ló ṣe ìṣìnà ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì fún wọn ní ìrètí asán nípa ẹ̀mí gígùn.
Ìyẹn nítorí pé (àwọn aláìsàn ọkàn) ń sọ fún àwọn t’ó kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ pé: "Àwa yóò tẹ̀lé yin nínú apá kan ọ̀rọ̀ náà." Allāhu sì mọ àṣírí wọn.
Báwo ni (ó ṣe máa rí) nígbà tí àwọn mọlāika bá gba ẹ̀mí wọn, tí wọn yó sì máa gbá ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn?
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n tẹ̀lé ohun tí ó bí Allāhu nínú. Wọ́n sì tún kórira ìyọ́nú Rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu ti ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́.
Tàbí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn ń lérò pé Allāhu kò níí ṣe àfihàn àdìsọ́kàn burúkú wọn ni?
Àti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n nípa ìpẹ́kọrọ-sọ̀rọ̀ (wọn). Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín.
____________________
Ìyẹn ni pé, àwọn aláìsàn-ọkàn máa ń pẹ́kọrọ nínú ìsọ̀rọ̀ wọn. Wọn kò sì níí rìn sàn-án lórí ọ̀rọ̀.
Dájúdájú A máa dan yín wò títí A fi máa ṣàfi hàn àwọn olùjagun-ẹ̀sìn àti àwọn onísùúrù nínú yín. A sì máa gbìdánwò àwọn ìró yín.
____________________
Àwọn ìró yín ni àwọn ìròyìn tí àwọn ènìyàn fi mọ̀ yín nípa ìṣọwọ́-ṣẹ̀sìn yín àti àwọn àdìsọ́kàn yín.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n tún kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, wọn kò lè kó ìnira kiní kan bá Allāhu. (Allāhu) yó sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ náà, kí ẹ sì má ṣe ba àwọn iṣẹ́ yín jẹ́.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, lẹ́yìn náà tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.
Ẹ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín.
____________________
Lẹ́yìn tí ìtayọ ẹnu-àlà ti wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb sí àwa mùsùlùmí, tí wọ́n ti fọwọ́ ara wọn fa ogun, tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ti pa á láṣẹ fún àwa mùsùlùmí láti jàjà gbára fún ẹ̀sìn wa, ẹ̀mí wa àti dúkìá wa, ogun ẹ̀sìn kò níí kásẹ̀ nílẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé àfi pẹ̀lú ọ̀kan nínú n̄ǹkan méjì; yálà kí àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn gba ’Islām nítorí pé, òhun nìkan ni ẹ̀sìn òdodo tàbí kí wọ́n máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām láì níí fi ẹ̀sìn irọ́ wọn dí àwa mùsùlùmí lọ́wọ́. Èyí ni òfin tí ó máa múlẹ̀ ní èyíkéyìí orílẹ̀-èdè ’Islām. Àmọ́ nígbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ kò níí sí owó ìsákọ́lẹ̀ mọ́ àfi gbígba ’Islām nìkan.
Eré àti ìranù ni ìṣẹ̀mí ayé. (Àmọ́) tí ẹ bá gbàgbọ́ (nínú Allāhu), tí ẹ sì bẹ̀rù (Rẹ̀), Ó máa fun yín ní àwọn ẹ̀san yín. Kò sì níí bèèrè àwọn dúkìá yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh).
Tí (Allāhu) bá bèèrè rẹ̀ ní ọwọ́ yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh), tí Ó sì won̄koko mọ yín, ẹ máa ṣahun. Ó sì máa mú àrùn ọkàn yín jadé (àṣírí yín yó sì tú síta).
Ẹ̀yin náà mà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń pè láti náwó fún ẹ̀sìn Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni t’ó ń ṣahun wà nínú yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣahun, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu ni Ọ lọ́rọ̀. Ẹ̀yin sì ni aláìní. Tí ẹ bá gbúnrí, (Allāhu) máa fi ìjọ mìíràn pààrọ̀ yín. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dà bí irú yin.
السورة التالية
Icon