0:00
0:00

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun t’ó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.
Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé).
Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run).
Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi gbígbóná mu.
Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.
Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.
Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.
(Ó máa) wà nínú Ọ gbà Ìdẹ̀ra gíga.
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.
Omi ìṣẹ́lẹ̀rú t’ó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.
Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,
àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),
àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,
àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.
Nítorí náà, ṣé wọn kò wo ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;
àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;
àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);
àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ ní gban̄sasa?
Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.
Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.
Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó tóbi jùlọ.
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.
السورة التالية
Icon