Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn t’ó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (t’ó lè jogún ara wọn). Àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (t’ó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fun yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ tí àwọn mùsùlùmí di alátìpó sínú ìlú Mọdīnah, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń fa ará Mọkkah kọ̀ọ̀kan lé ará Mọdīnah kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti sọ́ra wọn di ọ̀rẹ́ t’ó máa fẹ́ẹ̀ dà bí ẹbí. Nípasẹ̀ èyí, ìkíní kejì ń jogún ara wọn lẹ́yìn ikú. Ní àsìkò yìí, àwọn tí kò ì kúrò nínú Mọkkah láti wá ṣe àtìpó ní ìlú Mọdīnah nínú àwọn mùsùlùmí di ẹni tí kò lè jogún ẹbí rẹ̀ t’ó wà nínú ìlú Mọdīnah àfi tí òun náà bá gbé ìlú Mọkkah jù sílẹ̀. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, hijrah ṣíṣe sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ láti inú ẹbí kan fún ẹni t’ó ṣe hijrah. Àìṣe hijrah sì sọ ogún jíjẹ di èèwọ̀ láti inú ẹbí kan náà fún ẹni tí kò ṣe hijrah, wọn ìbáà dìjọ jẹ́ mùsùlùmi. Fífi hijrah sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ sì wà bẹ́ẹ̀ títí wọ́n fi ṣí ìlú Mọkkah. Níkété tí wọ́n ṣí ìlú Mọkkah, tí hijrah ṣíṣe láti Mọkkah Alápọ̀n-ọ́nlé sí Mọdinah Onímọ̀ọ́lẹ̀ kásẹ̀ nílẹ́, nígbà náà ẹbí nìkan l’ó ní ìpín àdáyanrí nínú ogún ẹbí rẹ̀. Wọn kò si fi hijrah ṣíṣe pín ogún fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní ìbámu sí āyah 75 nínú sūrah yìí. Lẹ́yìn náà, àwọn āyah ogún pípín fún àwọn ẹbí sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’.