Allāhu sọ pé: “Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan.”
____________________
Nínú èdè Lárúbáwá, wọ́n lè pe ọmọ ẹni ní iṣẹ́ ọwọ́ ẹni. Ní èdè Lárúbáwá èyí lè jẹ́ ‘amal tàbí kasb. Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Dájúdájú n̄ǹkan t’ó dára jùlọ ni n̄ǹkan tí ẹ bá jẹ nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín. Dájúdájú nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín ni àwọn ọmọ yín wà. (Sunan at-Tirmithiy; 1358. Abu ‘Īsā at-Tirmithiy sọ pé: “Èyí ni hadīth t’ó dára, t’ó fẹsẹ̀ rìnlẹ̀.)