Allāhu ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.
____________________
Àwọn sūfī (Tijāniyyah) ṣi āyah yìí àti tinú sūrah an-Nahl; 16:49 tú lábẹ́ àdìsọ́kàn wọn tí wọ́n ń pè ní “‘Ilmu bātiniy” – “Ìmọ̀ Awo-inú”. Àwọn sūfī (Tijāniyyah) sọ pé, pẹ̀lú àwọn āyah méjèèjì wọ̀nyẹn, “gbogbo olùjọ́sìn tàbí olùforíkanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu lójú-ìta, kò jọ́sìn kò sì forí kanlẹ̀ fún kiní kan àfi Allāhu (ta‘ālā) nítorí pé Òun l’Ó wà nínú àwọn aṣọ wọ̀nyẹn.” Irọ́ ńlá nìyí. Mímọ́ sì ni fún Allāhu tayọ ìsọkúsọ wọn yẹn. Āyah onípọ́n-na ni āyah méjèèjì wọ̀nyẹn. Pọ́n-na inú wọn ni pé, kò sí ẹni tí kì í forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Èyí ni àwọn sūfī ṣe àfikún rẹ̀ pé, “Kódà kí ó forí kanlẹ̀ fún òrìṣà, Allāhu nínú àwòrán òrìṣà l’ó ń forí kanlẹ̀ fún!” Kíyè sí i, ìgbàkígbà tí a bá rí āyah onípọ́n-na, āyah aláìnípọ́n-na ni a máa fi yanjú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi èyí rinlẹ̀ nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7. Nítorí náà, sūrah al-Hajj;22:18 àti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98 ti yọ pọ́n-na tí ó jẹyọ nínú āyah méjèèjì náà. Ní ti sūrah al-Hajj;22:18, òhun fi rinlẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Ní ti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98, òhun sì fi rinlẹ̀ pé àwọn t’ó ń forí kanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, àti àwọn àti òrìṣà wọn l’ó máa wọ inú Iná nítorí pé, wọn kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu, wọn kò sì jọ́sìn fún Un. Èyí ti túmọ̀ sí pé, sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49 kò kan olùforíkanlẹ̀ àti olùjọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu. Nítorí náà, gbólóhùn “wọ́n fẹ́” dúró fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo; “wọ́n kọ̀” sì dúró fún àwọn munāfiki. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Rūm; 30:26.


الصفحة التالية
Icon