Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà.
____________________
Kí ni n̄ǹkan tí Allāhu ń parẹ́?. Ki sì ni n̄ǹkan tí Ó ń mú ṣẹ? Ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan náà. Àgbọ́yé kìíní tí ó tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ ni pé, āyah náà jẹ́ àlàyé fún āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀. Ìdí ni pé, āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀ ń tọ́ka sí bí ó ṣe jẹ́ pé ọjọ́ ìyà, tí ó jẹ́ “àmì kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā)”, èyí tí ó máa kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ti ṣe wà nínú àkọsílẹ̀. Āyah 39 yìí wá ń sọ pé ní ọjọ́kọ́jọ́ tí ìyà náà bá ń dé sí àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́rùn, ó ń bẹ nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó máa bá ìyà náà lọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tí ìyà náà yóò dá sí títí dí ọjọ́ mìíràn. Àti ẹni tí ó máa bá ìyà lọ àtí ẹni tí ọjọ́ ìyà rẹ̀ yóò sún ṣíwájú, gbogbo rẹ̀ ni ó kúkú ti wà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ, tí í ṣe àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá bá ìyà lọ ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá ru ìyà náà là títí di ọjọ́ mìíràn ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Lẹ́yìn àgbọ́yé yìí ní ọ̀rọ̀ kan àwọn àgbọ́yé tí ó dá āyah náà tú lọ́tọ̀, láì sopọ̀ mọ́ āyah 38.
Àgbọ́yé kejì: Inú àkọsílẹ̀ méjì ni kádàrá ẹ̀dá wà. Àkọsílẹ̀ kan wà lọ́dọ̀ àwọn mọlāika. Àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika ni àkọsílẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń gbé fún wọn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ní ọdọọdún nínú Òru Abiyì (Laelatul-Ƙọdr). Ìyípadà lè ṣẹlẹ̀ sí kádàrá ẹ̀dá nínú àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika nípa ki ohun titun tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ lórí àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá kan. Bákàn náà, àwọn àlámòrí kan lè wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín. Àkọsílẹ̀ kejì ni àkọsílẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àkọsílẹ̀ yìí l’ó kó gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá sínú tán pátápátá, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ẹ̀dá kò tí ì máa jẹ́ ẹ̀dá títí dé ìkángun ẹ̀dá nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra tàbí nínú Iná. Nínú àkọsílẹ̀ yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ń yọ àkọsílẹ̀ ọlọ́dọọdún fún àwọn mọlāika Rẹ̀. Nítorí náà, ohun titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ohun tí ó bá wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Àmọ́ àti ohun titun àti èyí tí kò titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika, ìkíní kejì l’ó wà bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ.
Àgbọ́yé kẹta: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, kí ọkùnrin kan ti máa tẹ̀lé àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìyapa àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìṣìnà àìgbàgbọ́. Onítọ̀ún ni ẹni tí Allāhu pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ nínú ìmọ̀nà. Irúfẹ́ ẹni yìí l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí Allāhu fí orúkọ rẹ̀ rinlẹ̀ sínú ìmọ̀nà ni kí ọkùnrin kan ti máa yapa àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìmọ̀nà ’Islām. Onítọ̀ún l’ó wà ní abẹ́ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé kẹrin: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn mọlāika yóò máa kọ gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ̀dá sílẹ̀ ní ojoojúmọ́. Nígbà tí ó bá dí ọjọ́ Àlàmísì, wọn yóò yọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mo jẹ; mo mu; mo sùn; mo jí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ”. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’” Wọn yó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yòókù tí ó la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀dá. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé karùn-ún: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn āyah kan ń bẹ lásìkò tí al-Ƙur’ān ń sọ̀kalẹ̀ lọ́wọ́ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí Allāhu yóò pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ sì l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn āyah kan sì ń bẹ tí Allāhu kò níí pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ l’ó sì wà ní abẹ́ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé kẹfà: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yóò máa ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan fún ẹ̀dá. Èyí sì ni "yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’". Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yó sì fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan mú ẹ̀dá. Èyí sì ni "wa yuthbit".
Gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí wà nínú tafsīr at-Tọbarīy. Nítorí náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí yíyí kádàrá ẹ̀dá padà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Ó sì kúkú ti rinlẹ̀ nínú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé: “ A ti gbé gègé sókè kúrò lórí kíkọ kádàrá. Àwọn àkọsílẹ̀ sì ti gbẹ.” Ìyẹn nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Èyí sì l’ó ko gbogbo kádàrá ẹ̀dá sínú pátápátá àti gbogbo àwọn tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w.). Fún ìdí èyí àdúà tí ẹ̀dá yóò ṣe àti ọ̀nà tí àdúà náà yó fi gbà, méjèèjì ti wà nínú kádàrá ẹ̀dá tí ó wà nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àti pé kò sí ẹ̀dá t’ó nímọ̀ èwo nínú àwọn oore ayé àti tọ̀run l’ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àdúà. Èyí jẹ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ní abala kan. Ó tún jẹ́ ọlá fún àdúà ṣíṣe lábala kan nítorí pé oore àdúà ọ̀tọ̀, oore ẹ̀bùn Ọlọ́hun ọ̀tọ̀. Nítorí náà, gbogbo gbígbà àdúà wà ní abẹ́ àkọsílẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti kọ lé ẹ̀dá lórí nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀.


الصفحة التالية
Icon