Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè. Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò gbé wọn dìde.
____________________
Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀rí ìjọ Ahmadiyyah àti àwọn irú wọn gbogbo lórí ìgbàgbọ́ wọn pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú, kò sì níí padà wá sílé ayé mọ́ ni gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.”. Àwọn wọ̀nyí ń fi rinlẹ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé āyah 20 t’ó ṣíwájú gbólóhùn náà ń sọ nípa ipò tí àwọn n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn sọ di olúwa àti ọlọ́hun wọn lẹ́yìn Allāhu wà, ìyẹn ni pé, wọn kò lè dá ẹ̀dá kan àti pé òkú ni wọ́n, wọ́n ní nígbà náà, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú nítorí pé, òun náà wà lára n̄ǹkan tí àwọn kan sọ di ọlọ́hun, olúwa àti olùgbàlà. Wọ́n fi kún un pé, “Ṣebí Ànábì ‘Īsā náà kò lè dá n̄ǹkan kan.”
Ọ̀rọ̀ wọn yìí jìnnà sí òtítọ́. Àti pé wọ́n ti gbé gbólóhùn náà tayọ ẹnu-àlà. Wọ́n sì ti fi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Èyí t’ó jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ ni pé, gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.” kò sọ ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ohun t’ó ti ṣẹlẹ̀. Ṣebí àwọn mọlāika kan wà lára n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣé òkú ni àwọn mọlaika náà ni tàbí alààyè? A ò kúkú tí ì gbọ́ ikú mọlaika kan kan rí. Bákan náà, aṣ-Ṣatọ̄n ar-Rọjīm jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún. Ṣé òkú ni Ṣaetọ̄n náà ni tàbí alààyè? Rárá, kò ì kú. Síwájú sí i, àwọn ènìyàn kan ń jọ́sìn fún òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀. Ṣé wọ́n ti gbọ́ ikú tiwọn náà ni? Kò sí ọ̀kan nínú wọn t’ó tí ì di òkú. Kódà a kúkú rí àwọn ọlọ́hun mìíràn t’ó jẹ́ pé láti ojú-ayé wọn ni àwọn ẹ̀dá kan ti ń jọ́sìn fún wọn lẹ́yìn Allāhu. Àpẹẹrẹ irú wọn ni “Sati Guru Maraj” tí ó sọ ara di ọlọ́hun nínú ìlú Ìbàdàn. Alààyè ni ọ̀gbẹni náà, kò ì tí ì kú, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kú ni l’ọ́jọ́ ti àkókò ikú rẹ̀ bá dé ni.
L’ódodo ni pé àwọn kristiẹni ti sọ Jésù Kristi di ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún, àmọ́ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò ì kù. Ó sì wà nípò alààyè nínú sánmọ̀, bí Allāhu ṣe fẹ́.” Kò wá sí ẹ̀rí tààrà kan kan t’ó fi rinlẹ̀ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú bí kò ṣe āyah onípọ́nna èyí tí a ti ṣe àlàyé lórí rẹ̀ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n 3:55. Dípò kí á rí āyah kan tàbí hadīth kan tààrà lórí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), hadīth t’ó ń fi ìpadàbọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ l’à ń rí. Ẹni tí kò ì kú l’ó sì lè padà wá sílé ayé.
Kí wá ni èròǹgbà Allāhu lórí gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n),”? Ìtúmọ̀ àkànlò èdè l’ó wà fún gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n),” nínú āyah náà, kì í ṣe ìtúmọ̀ àdámọ́. Ìdí ni pé, nígbà tí kò bá sí ìwúlò kan kan tí a lè rí lára ẹ̀dá, irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ti wà nípò ẹni tí a lè ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú “òkú” nítorí pé òkú ni kò ní àǹfààní kan tí ó lè ṣe fún ara rẹ̀ àti fún àwọn alààyè. Nítorí náà, Allāhu ń fi gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.” pe làákàyè gbogbo ẹnikẹ́ni t’o ń jọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ pé kò sí àǹfààní kan kan tí irú olùjọ́sìn náà lè rí lọ́dọ̀ n̄ǹkan t’ó sọ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, gẹ́gẹ́ bí alààyè kò ṣe lè rí àǹfààní kan kan láti ara òkú.
Wàyí níwọ̀n ìgbà tí àwọn kristiẹni náà ti sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, kò sí àǹfààní kan tàbí oore kan tí ó lè ṣe fún wọn, wọn ìbáà pariwo orúkọ Jésù Kristi àti ẹ̀jẹ̀ Jésù nígbà igba. Àpẹẹrẹ àyè mìíràn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti lo kalmọh “òkú” àmọ́ tí kò fi ọ̀nà kan kan túmọ̀ sí “ẹni tí ó ti kú” bí kò ṣe ẹni tí kò lè ṣàǹfààní fún ara rẹ̀ àti fún ẹlòmíìràn ni sūrah al-’Ani‘ām; 6:122.
Bákan náà, Allāhu pe àwọn òrìṣà ní òkú nítorí pé, ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú, ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, ẹni tí kò lè ríran, ẹni tí kò lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́ ni ipò tí gbogbo ère òrìṣà wà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ère Jésù Kristi àti igi àgbélébùú rẹ̀ tí wọ́n gbẹ́, tí wọ́n ń jọ́sìn fún, kò lè sọ̀rọ̀, kò lè ríran, kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́.