A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì. Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga t’ó tóbi.”
____________________
Ìbàjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn Ọmọ ’Isrọ̄’īl ní sísọ ogun àsọtẹ́lẹ̀ ni pípa tí wọ́n máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Zakariyyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti pípa tí wọ́n tún máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Wọ́n kúkú padà fọwọ́ ara wọn pa àwọn Ànábì méjèèjì náà ni, bàbá àti ọmọ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām).


الصفحة التالية
Icon