A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran1 nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò. Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.2
____________________
1 Àmì alẹ́ ni òṣùpá, àmì ọ̀sán ni òòrùn. Ní ìpìlẹ̀, àti òṣùpá àti òòrùn ni wọ́n dìjọ ní ìmọ́lẹ̀ irú kan náà; wọ́n sì dìjọ mọ́lẹ̀ gbòlà. Pẹ̀lú bí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti ìmọ́lẹ̀ òòrùn ṣe mọ́lẹ̀ gbòlà bákan náà yìí, kò lè rọrùn fún àwa ẹ̀dá láti rí oorun sùn, láti gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn, láti mọ ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ àti òpin ọjọ́ pẹ̀lú òǹkà ọdún. Àmọ́ nípasẹ̀ àánú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí wa, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa ìmọ́lẹ̀ gbòlà ti òṣùpá rẹ́. Ó sì ṣẹ́ ti òòrùn kù. Al-Hamdulillāh rọbbil-‘ālamīn. (Ẹ wo àlàyé yìí ní kíkún nínú al-Ƙurtubiy.) 2 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.