Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu- àlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san).
____________________
1 Àwọn ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ó lè mú kí ìjọba ’Islām pa ènìyàn ni kí ènìyàn jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè lẹ́yìn tí onítọ̀ún ti ní ọkọ tàbí aya, ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́ àti fífi ẹ̀sìn ’Islām sílẹ̀. 2 Ọ̀nà ìgbẹ̀san fún ẹ̀sùn ìpànìyàn wà nínú sūrah an-Nisā’; 4: 92-93 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:45