(Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré t’ó tóbi.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah àkọ́kọ́ t’ó bẹ̀rẹ̀ sūrah yìí fún àgbọ́yé āyah yìí. Bákan náà, híhù tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú igi zaƙūm hù jáde láti inú Iná jẹ́ ohun tí ó tako òye àwọn aláìgbàgbọ́. Wọ́n takò ó. Àtakò wọn sì di àdánwò fún wọn.


الصفحة التالية
Icon