Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Kí o sì ṣe ìlérí fún wọn." Èṣù kò sì níí ṣe ìlérí fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn.
____________________
Ohùn Èṣù ni orin àlùjó oníran-ànran, eré ṣíṣe àti ayò títa. Èṣù ń kópa pẹ̀lú ènìyàn nínú dúkìá nípa pé ènìyàn yóò máa wa ayé mọ́yà; wọn yóò máa kó dúkìá ayé jọ ní ọ̀nà harām; wọn yó sì máa ná dúkìá náà ní ìná àpà sí ọ̀nà harām. Èṣù ń kópa pẹ̀lú ènìyàn nínú ọmọ bíbí nípa pé àwọn òbí yóò máa sọ ọmọ di yẹhudi, kristiẹni tàbí abọ̀rìṣà; wọn yóò máa bí ọmọ nípasẹ̀ àgbèrè (sìná) ṣíṣe; wọn yó sì máa lo ọmọ ní ìlòkúlò. Èṣù ń ṣe ìlérí ẹ̀tàn fún àwọn ènìyàn nípa pé Èṣù yóò máa ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún ènìyàn oníran-ànran aburú, lílo òfin àti ìdájọ́ t’ó lòdì sí èyí tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ sínú àwọn Tírà Rẹ̀ (bí lílo òfin Democracy), níní àdìsọ́kàn burúkú nípa ẹ̀sìn ’Islām (bí àdìsọ́kàn Tijāniyyah, Ƙọ̄diriyyah àti Ahmadiyyah) àti níní àgbẹ́kẹ̀lé asán nínú òògùn ṣíṣe, idán pípa àti níní àgbẹ́kẹ̀lé asán nínú ìmóríbọ́ nínú ìyà ọ̀run ní Ọjọ́ Àjíǹde fún àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin àti àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ tí Èṣù ń lò fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ni gbogbo olùpèpè sínú ìyapa àṣẹ Allāhu àti àṣẹ àwọn Ànábì Rẹ̀ (‘aleehim sọlātun wa salām).


الصفحة التالية
Icon