Ní ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn. Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí ṣàbòsí bín-íntín sí wọn.
____________________
Aṣíwájú wọn nínú āyah yìí lè túmọ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí: Ànábì ìjọ kọ̀ọ̀kan, tàbí ẹni tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tẹ̀lé n’ílé ayé tàbí tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ìjọ kọ̀ọ̀kan tàbí ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.


الصفحة التالية
Icon