(Ànábì) Mūsā sọ fún un pé: “Ṣé kí n̄g tẹ̀lé ọ nítorí kí o lè kọ́ mi nínú ohun tí Wọ́n fi mọ̀ ọ́ ní ìmọ̀nà.”
____________________
Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lérò pé lílọ tí Ànábì Mūsā lọ sí ọ̀dọ̀ Kidr túmọ̀ sí pé Kidr lóore ju Ànábì Mūsā (a.s.w.) lọ lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Tí Kidr bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Allāhu “waliyyu-llāh”, ipò jíjẹ́ Ànábì jẹ́ oore àjùlọ lórí ipò jíjẹ́ waliyyu. Tí àwọn méjèèjì bá sí dìjọ jẹ́ Ànábì, fífún tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Mūsā ní Tírà tún jẹ́ oore àjùlọ mìíràn lórí Kidr. Àti pé Ànábì Mūsā (a.s.w.) tún ní oore àjùlọ mìíràn nípa bí ó tún ṣe jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn Òjíṣẹ́ tí a mọ̀ sí àwọn Onípinnú nínú àwọn Òjíṣẹ́ " ’ulul-‘azmi minar-Rusul" (a.s.w.).
Síwájú sí i, gbogbo mùsùlùmí ni waliyyu-llāh, àmọ́ bí mùsùlùmí kọ̀ọ̀kan bá ṣe súnmọ́ Allāhu tó, nínú ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù rẹ̀ nípa lílo òfin ẹ̀sìn ’Islām, l’ó máa ṣ’òdíwọ̀n ìsúnmọ́ tí ń bẹ láààrin Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) àti ẹrúsìn Rẹ̀ náà. Ṣíwájú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Allāhu fún àwọn mùsùlùmí kan ní àǹfààní láti rí ìṣípayá mímọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Lára àwọn tí Allāhu ṣe èyí fún ni ìyá Mūsā, Mọryam ìya ‘Īsā, Thul-Ƙọrneen àti Kidr. Ìṣípayá mímọ́ tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn yìí kò sọ wọ́n di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́. Àmọ́ wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ tí ìṣípayá mímọ́ náà mú wá fún wọn, bí àpẹẹrẹ, ìya Mūsā (r.ah) kò ṣàdédé gbé ọmọ rẹ̀, Ànábì Mūsā jù sínú odò, tí kì í bá ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó pa á láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìṣípayá mímọ́ tí Ó fi ránṣẹ́ sí i. Bákan náà, àwọn n̄ǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí Kidr dánwò lójú Ànábì Mūsā, ìbá tí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí kì í bá ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó pa á láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àǹfààní wọ̀nyí wà fún àwọn t’ó ṣíwájú Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ṣùgbọ́n kò sí fún ìjọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Èyí ni pé, lásìkò yìí ẹnì kan kan kò gbọdọ̀ lo òfin kan tí ó yapa sí òfin tí Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mú wá, kí ó wí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó fún òun náà ní ìṣípayá mímọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́ọ́rọ́wọ́ ni onítọ̀ún yóò jáde kúrò nínú ipò jíjẹ́ mùsùlùmí. Ọ̀wọ́ ẹnì kan ṣoṣo tí Allāhu ìbá fún ní ìṣípayá mímọ́ nínú ìjọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), òun ni ’Amīrul-mu’minīn, ‘Umar bun Kattọ̄b (r.a). Èyí wà ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tí ó sọ pé: “Dájúdájú ṣíwájú yín nínú àwọn ọmọ ‘Isrọ̄’īl, ni a ti rí àwọn ènìyàn kan tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (ní ti ìṣípayá mímọ́), wọn kì í sì ṣe Ànábì. Tí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan nínú wọn máa wà nínú ìjọ mi ni, ‘Umar ni ìbá jẹ́." [Al-Bukāriy; bāb mọnāƙib ‘Umọr] Bákan náà, ohun tí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kọ́ lọ́dọ̀ Kidr kò túmọ̀ sí pé ó kọ́ ọ fún lílò láààrin ìjọ rẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní òfin àti ìlànà tirẹ̀ nínú ’Islām, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún un láti lo òfin àti ìlànà tí Allāhu fún Kidr, yálà Kidr jẹ́ waliyyu tàbí Ànábì. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Hajj; 22:67. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nípa ìrìn-àjò rẹ̀ sọ́dọ̀ Kidr ni pé, ìmọ̀ nípa òfin àti ìlànà ’Islām, èyí tí Allāhu fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra wọn díẹ̀díẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Ànábì kan sí òmíràn. Àti pé kò rọrùn fún ẹnì kan nínú wọn láti jẹ́ alámọ̀tán ohun gbogbo. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìkan ṣoṣo sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.


الصفحة التالية
Icon