(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”
____________________
Àwọn kristiẹni ń sọ pé Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ni al-Ƙur’ān pè ní “ẹni mímọ́” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah yìí. Èsì ní ṣókí ni pé, ní òdodo ẹni mímọ́ ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kì í ṣe òun nìkan ni ẹni mímọ́. Āayah 13 nínú sūrah yìí kan náà pe Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹni mímọ́. Bákan náà, ọmọ tí àsọọ́lẹ̀ wáyé lórí rẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 17:81, ẹni mímọ́ ni al-Ƙur’ān pe òun náà. Báwo ni jíjẹ́ ẹni mímọ́ Jésù ṣe máa sọ ọ́ di olúwa àti olùgbàlà nígbà tí jíjẹ́ ẹni mímọ́ àwọn méjèèjì wọ̀nyẹn kò sọ wọ́n di bẹ́ẹ̀. Sì kíyè sì i, gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nínú al-Ƙur’ān ni ẹni mímọ́. Àti pé ìdà kejì ẹni mímọ́ ni ẹni àìmọ́. Báwo ni Ọlọ́hun ṣe máa fi iṣẹ́ mímọ́ rán ẹni àìmọ́? Kò lè ṣẹlẹ̀. Ṣíwájú sí i, nínú èdè Lárúbáwá, ìsọdorúkọ olùṣe fún “ẹni mímọ́” ni “zakiyyun”, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ fún “mímọ́” ni “zakāt”. Ìgbà tí ìròyìn bá bùáyà tán lára ẹni tí a fẹ́ pọ́n ní àpọ́npo, dípò kí Lárúbáwá lo ìsọdorúkọ olùṣe fún irú ẹni náà, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ ni wọ́n máa lò. Ìyẹn ni pé, jíjẹ́ ẹni mímọ́ t’ó lágbára gan-an ni ìlò èdè tí aL-Ƙur’ān lò fún Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ọmọ alásọọ́lẹ̀ náà. Àfijọ èyí nínú ìlò èdè Yorùbá, bí àpẹẹrẹ, ni ìyàtọ̀ t’ó wà láààrin kí á pe ẹni kan ní olówó àti owó. Nígbà tí owó olówó kan bá ń pe àwọn olówó ńláńlá ránṣẹ́, l’a máa pe ẹni náà pé “Owó ni lágbájá.” Ta wá ni ó mọ́ jùlọ láààrin “zakiyyu” t’ó túmọ̀ sí “ẹni mímọ́” àti “zakāt” t’ó túmọ̀ sí “mímọ́”? Kò wa tán bí!


الصفحة التالية
Icon