(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: "Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ni Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì.
____________________
Ẹrú Allāhu ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ àwọn kristiẹni kò gbàgbọ́ pé ẹrú Allāhu ni. Wọ́n ní, “ọmọ Ọlọ́hun ni.” Kódà àwọn náà sọra wọn di ọmọ Ọlọ́hun. Kí ni ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò sí ọ̀rọ̀ mìíràn fún ìdàkejì ẹrú bí kò ṣe “ọmọ”. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “Bí ẹrú bá pẹ́ títí ẹrú á dọmọ”. Dọmọ ta ni? Ẹrú a dọmọ bàbá rẹ̀ nítorí pé, “ọ̀nà ló jìn, ẹrú ní baba”. Kí wá ni ọ̀rọ̀ mìíràn fún “ọmọ”? Ọmọ ni ẹni tí kò sí lóko-ẹrú. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ mìíràn fún ọmọ àti òbí tí kò sí lóko ẹrú ni “olómìnira”.
Ní ọ̀dọ̀ àwa mùsùlùmí, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” nìyí: “Ẹ̀dá tí ó ń tẹ̀lé ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn t’ó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn, ó ti sọra rẹ̀ di ẹrú rẹ̀, láì la wíwà ní oko-ẹrú lọ bíi ti ẹrú àfowórà tàbí ẹrú ogun. Èyí fi hàn pé, ẹrú ẹ̀dá yàtọ̀ sí ẹrú Ọlọ́hun.
Àwọn òǹkọ-bíbèlí mọ̀ọ́mọ̀ yọ “ẹrú Ọlọ́hun” kúrò nínú bíbélì òde-òní. Wọ́n sì fi “ọmọ Ọlọ́hun” rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe lè sin òkú àbòsí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò níí yọ sílẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi rí ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” kà nínú ìwé Róòmù 7:25 báyìí pé: “So then, with my mind I am a slave to the law of God, but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà, pẹ̀lú ẹ̀mí mi, ẹrú ni mi sí òfin Ọlọ́hun, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹran ara mi, ẹrú ni mi sí òfin ẹ̀ṣẹ̀. (New Revised Standard Version àti New International Version) Ìyẹn ni pé, tí ìwọ bá tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin Ọlọ́hun. Tí ìwọ bá sì tẹ̀lé òfin ẹ̀ṣẹ̀, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Jésù Kristi ti tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú Ọlọ́hun ni Jésù Kristi. Tàbí ẹnu àwọn kristiẹni gbà á láti sọ pé Jésù Kristi kò lo òfin àti ìlànà Ọlọ́hun? Rárá. Tàbí ẹnu àwọn kristiẹni gbà á láti sọ pé òfin ẹ̀ṣẹ̀ ni Jésù Kristi tẹ̀lé? Rárá. Kò kúkú sí ìkẹta, lẹ́yìn òfin Ọlọ́hun, òfin èṣù ló tún kù. Jésù Kristi kò sì lo òfin Èṣù rí nínú ayé rẹ̀.
Àwa mùsùlùmí kú orí ire. Ọpẹ́ sì ni fún Ọlọ́hun t’ó jẹ́ kí á dá bàbá wa mọ̀ lọ́tọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́hun. Bákan náà, ẹ̀rù kò bà wá láti pe ara wa ní ẹrú Ọlọ́hun níbikíbi nítorí pé, pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn, ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn, Olùgba-ìrònúpìwàdà sì ni Allāhu.