Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.
____________________
Nígbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” bíi “A” tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ bíi “Àwa” fún Ara Rẹ̀, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àpọ́nlé fún Un, kì í ṣe pé Ẹni t’Ó ń jẹ́ “Allāhu” pé méjì tàbí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ “ọ̀pọ̀” náà ń dúró fún iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń dá ṣe pẹ̀lú gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀” tàbí iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa yan àwọn mọlāika Rẹ̀ láti ṣe. Ní ti āyah 68 àti 69, àwọn mọlāika ni Allāhu máa pàṣẹ iṣẹ́ wọ̀nyẹn fún lọ́jọ́ Àjíǹde. Àwọn mọlāika náà sì ni ẹ̀ṣọ́ Ina. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah at-Tahrim; 66:6 àti sūrah al-Mudaththir; 74:30-31. Bákan náà, kalmọh “wārid” t’ó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ méjì péré l’ó wà fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd; 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98-100. “Warada” tún túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, àmọ́ kò wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:23. Ìtúmọ̀ méjèèjì wọ̀nyí ti fi hàn kedere pé kò sí ẹ̀dá tí kò níí dé ibi tí Iná wà lọ́jọ́ Àjíǹde. Àmọ́ àwọn kan máa “débẹ̀ wọbẹ̀”, àwọn kan sì máa “débẹ̀ láì wọbẹ̀”. Ìdí tí gbogbo ẹ̀dá máa fi dé ibi tí Iná wà ni pé, ojú ọ̀nà tí a máa tọ̀ dé ibi tí Ọgbà Ìdẹ̀ra wà ni Iná wà. Ìsàlẹ̀ lọ́wọ́ iwájú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni Allāhu fi àyè Iná sí. Kódà, ọ̀nà tí a máa tọ̀ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sì jẹ́ afárá tẹ́ẹ́rẹ́ yíyọ̀ lórí Iná. Igun mẹ́ta sì ni àwọn ènìyàn àti àlùjọ̀nnú máa pín sí lórí ìrìn wọn lórí afárá Iná. Igun kìíní ni àwọn Ànábì, àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.) àti àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, t’ó máa rìn lórí afárá Iná láì níí jábọ́ sínú Iná títí wọ́n fi máa gúnlẹ̀ sínú ilé ìgbàlà wọn, Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Kí Allāhu fi àánú Rẹ̀ ta wá lọ́rẹ àrìnyè náà.). Igun yìí ni Allāhu ti ṣe àforíjìn fún pátápátá lórí àṣìṣe wọn. Ṣebí kò sí bí a ó ṣe rìn tí orí kò níí mì lọ̀rọ̀ ẹ̀dá nílé ayé. Allāhu sì ni Aláforíjìn ẹ̀dá. Igun kìíní yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa wọn nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:101-102 àti sūrah az-Zumọr; 39:61. Igun kejì ni àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, t’ó máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́ sínú Iná. Igun yìí ni wọ́n ní àwọn àṣìṣe kan lọ́rùn, àmọ́ tí Allāhu kò forí rẹ̀ jìn wọ́n. Sebí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú ti sọ pé kí ẹni tí ó bá ń dá ẹṣẹ̀, tí kò tọrọ àforíjìn tàbí ronú pìwàdà lórí rẹ̀ títí ó fi kú má ṣe fọkàn balẹ̀ pé Òun kúkú máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fìyà ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:116. Igun kejì yìí l’ó máa padà jáde kúrò nínú Iná lásìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́, yálà nípasẹ̀ ìṣìpẹ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí nípasẹ̀ àánú àti ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Igun kẹta ni igun gbogbo ẹni tí ó kú sórí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹbọ tàbí ìṣojúméjì pẹ̀lú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Igun kẹta yìí náà máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́, àmọ́ wọn kò níí jáde kúrò nínú rẹ̀ títí láéláé nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí ṣíjú àánú wò wọ́n rárá. Nítorí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí Iná kò níí jó nítorí gbólóhùn “wa ’in minkum ’illā wāriduhā”, ẹni náà ti sọ̀rọ̀ àìmọ̀kan t’ó gbópọn lẹnu nítorí pé, ó ti fi ìtúmọ̀ “warada” mọ sórí “ó débẹ̀ wọbẹ̀” nìkan, ó sì kọ̀yìn sí ìtúmọ̀ “warada” t’ó túmọ̀ sí “ó débẹ̀ kò wọbẹ̀”. Irú ẹni náà sì súnmọ́ kí ó jẹ́ kristiẹni, olùṣìnà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó bá sọ pé kò sí igun kan kan tí ó máa padà jáde kúrò nínú Iná. Kò sí ẹni tí ó máa sọ bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí ó máa wà nínú Iná gbére, irú ẹni náà ti sọ ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah t’ó ń fi Iná gbere rinlẹ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́. Irú ẹni náà súnmọ́ k’ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah.
Lẹ́yìn náà, yálà igun tí ó máa rin àrìnyè lórí afárá Iná tàbí igun tí ó máa rin àrìnjábọ́ sínú Inȧ, igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé, àwọn mọlāika kan l’ó máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé, kò sí ẹ̀dá kan t’ó máa fẹ́ fínnú fíndọ̀ gba orí afárá Iná kọjá. Dándan sì ni fún gbogbo wọn láti gba orí rẹ̀ kọjá bọ́ sí àyè wọn. Àwọn mọlāika wọ̀nyẹn ni àwọn mọlāika agbèrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àwọn mọlāika agbèrò Iná. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún fi rinlẹ̀ nínú sūrah az-Zumọr; 39:71-73.