Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
____________________
Ìdí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi pa á láṣẹ fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Mọs‘ūd (rọdiyallāhu 'anhu) ṣe gbà á wá, ni pé awọ òkúǹbete kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọn kò pa lósè ni wọ́n fi ṣe bàtà náà. Àmọ́ nínú sunnah Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), mùsùlùmí lè wọ bàtà kírun níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti pa awọ rẹ̀ lósè, tí kò sì níí kó ìnira bá ẹnikẹ́ni lórí ìrun, tí kò sì níí kó ìdọ̀tí wọ inú mọ́sálásí. Ọ̀kan nínú ìrun tí èyí lè ti rọrùn jùlọ ni ìrun tí a kí ní orí ilẹ̀ gban̄sasa bí mọ́sálásí eléruku, ìrun ‘Īd méjèèjì, ìrun jannāzah àti ìrun ìwá òjò.