A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kò níí jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).
____________________
Àwọn t’ó gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú sọ pé, “Āyah yìí àti āyah 34 níwájú tako àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé. Nítorí náà, Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú”.
Èsì: Kíyè sí i! Gbígbé tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lọ sínú sánmọ̀ kò túmọ̀ sí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò níí kú. Rárá o, ó máa kú lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ nítorí pé, abara ni, kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu, Ọlọ́hun nìkan ni kò níí kú láéláé. Yàtọ̀ sí āyah “ƙọbla maotih” nínú sūrah an-Nisā’; 4:159, àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti fi rinlẹ̀ pé, ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹ̀yìn ìgbà tí ó bá t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀, ìyẹn ní òpin ayé. Ohun tí ó kàn jẹ́ ìṣòro fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ṣíwájú àsìkò yìí ni pé, bí wọ́n bá sọ pé kò sí āyah tààrà kan lórí àìtíìkú rẹ̀ àti ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀ láti ojú sánmọ̀ lópin ayé, kò sí ìmọ̀ t’ó yè kooro fún wọn lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Nítorí pé, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀kọ́ t’ó yè kooro lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), wọn ìbá mọ̀ pé dájúdájú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní òmìnira láti sọ ọ̀rọ̀ tí kò sí nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ní òdíwọ̀n ìgbà tí hadīth bẹ́ẹ̀ bá sì ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa hadīth, ẹnu aláìmọ̀kan tàbí aláààbọ̀ ẹ̀kọ́ kan kan kò sì gbà á láti tako irúfẹ́ àwọn hadīth náà. Bí ó bá dán an wò pẹ̀rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti bàjẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4: 115.
Bí àpẹẹrẹ, al-Ƙur’ān fi rinlẹ̀ pé, àwọn òkú kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè ní ìbámu sí sūrah an-Naml; 27:80, sūrah ar-Rūm; 30:52 àti sūrah Fātir; 35:22. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì padà di òkú tí wọ́n bò mọ́ inú sàréè nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:30. Kò sì sí āyah tààrà kan nínú al-Ƙur’ān tí ó yọ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sílẹ̀ nínú àwọn òkú tí kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè. Àmọ́ hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń dá sálámọ̀ padà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá sálámọ̀ sí i nídìí sàréè rẹ̀. Kódà hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ tún wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, ní gbogbo ọjọ́ Jímọ̀, àwọn mọlāika ń gbé ìtọrọ-ìkẹ́ àti ìtọrọ-ìbùkún fún Ànábì wa Muhammad sí etí ìgbọ́ rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀ láti ibikíbi nílé ayé tí wọ́n bá ti ń tọrọ rẹ̀ fún un (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
Hadīth kìíní: Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé, “Kò sí ẹnì kan tí ó máa sálámọ̀ sí mi àfi kí Allāhu dá ẹ̀mí mi padà sí mi lára títí mo máa fi dá sálámọ̀ náà padà fún un.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb ziyāratul-ƙubūr. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà dára”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Hadīth kejì: Láti ọ̀dọ̀ ’Aos ọmọ ’Aos (rọdiyallāhu 'anhu), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé, “Dájúdájú ọjọ́ Jum‘ah wà nínú àwọn ọjọ́ yín t’ó lóore jùlọ; Wọ́n ṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú rẹ̀, Wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ nínú rẹ̀, ìfọn àkọ́kọ́ sínú ìwo máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Ikú gbogbo ẹ̀dá sì máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ asọlātu fún mi nínú rẹ̀ nítorí pé, wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn asọlātu yín sí ọ̀dọ̀ mi.” ’Aos sọ pé, àwọn Sọhābah wí pé, “Òjíṣẹ́ Allāhu, báwo ni wọ́n ṣe máa kó àwọn asọlātu wa wá bá ọ, ó ó má ti derùpẹ̀!?” Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ('azza wa jall.) ṣe ẹran ara àwọn Ànábì ní èèwọ̀ fún ilẹ̀.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb fọdli yaomil-Jum‘ah walaelatil-Jum‘ah. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà ní àlàáfíà”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Àpẹẹrẹ mìíràn ni àwọn hadīth tààrà t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ènìyàn hóró kan ṣoṣo tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pè ní “Mọsīhu-ddajjāl”. Ẹni yìí má yọjú sáyé lópin ayé. Ó sì máa fòòró ayé ní ìfòòró kan tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.
Àmọ́ tòhun ti bí “Mọsīhu-ddajjāl” ṣe jẹ́ ẹyọ kan nínú àwọn àmì ńlá fún òpin ayé, kò sí āyah kan tààrà lórí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan l’ó jẹ́ kí á mọ̀ pé ènìyàn kan ń bọ̀ lópin ayé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mọsīhu-ddajjāl.
Èyí sì ni ìgbàgbọ́ àti àdìsọ́kàn àwa mùsùlùmí, tòhun ti bí kò ṣe sí āyah t’ó gbè é lẹ́sẹ̀ tààrà nínú al-Ƙur’ān. Nígbà tí gbogbo àwa mùsùlùmí ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn irúfẹ́ àwọn hadīth òkè wọ̀nyẹn, ní ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó tayọ òye wa, àmọ́ tí ó tẹnu Ànábì wa Muhammad olódodo (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jáde, nígbà náà ta ni ẹni tí ó máa lórí láyà tako àwọn hadīth Bukọ̄riy àti hadith Muslim t’ó wá lórí àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé? Ẹnikẹ́ni tí ó bá takò ó ti tako Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ọ̀kan nìyí nínú àwọn hadīth náà.
Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Báwo ni ẹ̀yin máa wà nígbà tí Ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá sọ̀kalẹ̀ sáààrin yín, tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín.” Ẹnì kan nínú àwọn t’ó gba hadīth yìí wá sọ pé, “Kí ni ìtúmọ̀ “tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín”? Tàbí kí ni ìtúmọ̀ “tí ohun tí ó máa fi darí yín sì máa wá láti ọ̀dọ̀ yín?” Ibnu Abī Thanb sì fèsì pé, “Ó máa fi tírà Olúwa yín (tabāraka wa ta'ālā) àti sunnah Ànábì yín (sollalāhu 'alayhi wa sallam) darí yín.” Ni ìtúmọ̀ rẹ̀. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni “imām” dúró fún nínú hadīth yìí, gẹ́gẹ́ bí “imām” ṣé dúró fún “tírà” nínú sūrah Hūd; 11:17, sūrah al-’Ahƙọ̄f; 46:12 àti sūrah Yāsīn, 36:12.


الصفحة التالية
Icon