Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kò rí i pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀ pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀ pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti inú omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni?
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, sūrah Fussilat; 41:11 tako sūrah al-’Anbiyā’; 21:30.
Èsì: Kò sí ìtakora kan kan nínú āyah méjèèjì. Àlàyé rẹ̀ nìyí, ìtúmọ̀ “rọtƙ” ni “ìlẹ̀pọ̀, lílẹ̀-papọ̀”, ìtúmọ̀ “fatƙ” sì ni “ẹ̀là, lílà, yíyà”. Ní ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀dá sánmọ̀ àti ilẹ̀, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò fi ojú kan kan sára ìkíní kejì tí n̄ǹkan kan lè gba jáde síta. Lẹ́yìn náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) la ojú sánmọ̀ nítorí kí omi òjò lè máa tinú rẹ̀ jáde sí orí ilẹ̀. Allāhu sì tún la ojú ilẹ̀ nítorí kí irúgbìn lè máa tinú rẹ̀ jáde. Tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò bá ṣe èyí fún ìkíní kejì ni, òjò ìbá tí rí ọ̀nà jáde nínú sánmọ̀, irúgbìn ilẹ̀ náà ìbá tí rí ọ̀nà wù jáde nínú ilẹ̀. Ìdí nìyí tí gbólóhùn “A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti ara omi” fi parí āyah yẹn. Kíyè sí i, kalmọh ìlẹ̀pọ̀ tí Allāhu lò fún sánmọ̀ àti ilẹ̀, kò túmọ̀ sí pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’ó lẹ̀ papọ̀ mọ́ra wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wí bẹ́ẹ̀. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìkíní kejì wà. Ìdí sì nìyí tí ó fi jẹ́ pé, ìkíní kejì wọn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa àṣẹ fún láti máa mú ohun tí ó wà nínú wọn jáde. Èyí sì ni ó mú ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ wá ní “èjì”, dípò “ẹyọ”, fún sánmọ̀ àti ilẹ̀ nítorí pé, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìkíní kejì wọn wà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èyí sì l’ó jẹyọ nínú sūrah Fussilat; 41:11. Nítorí náà, kò sí ìtakora nínú àwọn āyah náà. W-Allāhu ’a‘lam.