A kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, Èṣù máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí Èṣù ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
yah 52 yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah pàtàkì tí àwọn kristiẹṅi máa ń tọ́ka sí láti fi tako al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé àti Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àwọn kristiẹni máa ń sọ pé, “Kókó t’ó wà nínú āyah náà ni pé, Èṣù máa ń gbé ọ̀rọ̀ sẹ́nu Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lásìkò tí ó bá fẹ́ ka al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn láti fi jíṣẹ́ fún wọn. Wọ́n fi kún un pé Èṣù l’ó máa ń gba ẹnu Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ̀rọ̀ nígbàkígbà tí ó bá ń jíṣẹ́ Ọlọ́hun.” Nítorí kí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn kristiẹni wọ̀nyí lè dùn létí àwọn ènìyàn, wọ́n túlé kan ẹ̀gbàwá ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ṣe àfitì rẹ̀ sọ́dọ̀ ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) pé, “Ní ọjọ́ kan Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń ka sūrah an-Najm, ìyẹn sūrah 53, fún àwọn ará ìlú Mọkkah. Nígbà tí ó ka sūrah náà dé orí āyah 19 sí āyah 20, ní àyè tí Allāhu (s..w.t.) ti sọ pé “Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā, àti òmíràn, Mọnāh, òrìṣà kẹta”, ó sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.” Nígbà tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ bẹ́ẹ̀ tán, gbogbo àwọn mùsùlùmí àti àwọn ọ̀ṣẹbọ sì dìjọ forí kanlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀…” Àwọn kristiẹni wá sọ pé, “àwọn òrìṣà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pè ní ẹyẹ àgbà ni ọ̀rọ̀ náà tí Èṣù jù sẹnu Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lásìkò t’ó ń ké al-Ƙur’ān náà. Ìtàn náà sì wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn tírà tafsīr àwọn mùsùlùmí.” Ọ̀rọ̀ wọn lórí ìtúmọ̀ tí wọ́n fún āyah 52 àti ẹ̀rí wọn lórí rẹ̀ parí.
Èsì ọ̀rọ̀: Ọ̀rọ̀ ńlá ni àwọn kristiẹni sọ yìí. Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe òdodo rárá. Àfiwé ìtúkútùú àwọn kristiẹni wọ̀nyí dà bí ọ̀rọ̀ arákùnrin wọn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Lákin”. Lákin yìí l’ó sọ pé òun náà nímọ̀ ìtúmọ̀ al-Ƙur’ān ju àwa mùsùlùmí lọ. Ó sì sọ pé kódà Allāhu dárúkọ òun nínú al-Ƙur’ān. A sì bi í léèrè pé ibo ni orúkọ rẹ̀ wà nínú al-Ƙur’ān. Ó sì fèsì pé orúkọ òun ni gbogbo ibi tí al-Ƙur’ān bá ti sọ pé “لَكِنْ” (lākin)!? Ẹ̀yin onímọ̀, ṣé ìtúmọ̀ “لَكِنْ” (lākin) nínú èdè Lárúbáwá sì ni ìtúmọ̀ “Lákin” nínú èdè Yorùbá? “Ṣùgbọ́n / àmọ́” ni ìtúmọ̀ “لَكِنْ” (lākin) nínú èdè Lárúbáwá. “Ẹni tí ó ní akin-ọkàn” sì ni ìtúmọ̀ “Lákin” nínú èdè Yorùbá. Ṣé ẹ rí i báyìí pé “ṣùgbọ́n” ti wọnú ọ̀rọ̀ àwọn kristiẹni. Ìyẹn ni pé, wọn kò ní ìmọ̀ olóóókan nípa al-Ƙur’ān àti hadīth, ṣùgbọ́n wọ́n mọ irọ́ funfun báláú pa mọ́ ẹ̀sìn ’Islām. Ìṣe wọn yìí sì ṣe wẹ́kú ọ̀rọ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Baƙọrah; 2: 78.
Wàyí tí a ti mọ irú ènìyàn tí àwọn kristiẹni í ṣe, ẹ jẹ́ kí á ṣàlàyé āyah tí wọ́n ń túmọ̀ sódì náà. Ní àkọ́kọ́ ná, ẹni tí Èṣù bá ń gbẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀, bí kò jẹ́ wèrè, ó máa jẹ́ eléṣù tí ó bá Èṣù dòwò pọ̀. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kì í ṣe wèrè. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò sì lọ́dẹ orí rí. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé kò bọ̀rìṣà rí áḿbọ̀sìbọ́sí pé Èṣù yóò máa gùn ún. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ti fi rinlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah al-Ƙur’ān pé Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò lágbára lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ni ọ̀gá àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Díẹ̀ nínú àwọn àyè tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ èyí ni sūrah al-Hijr; 15:42 àti sūrah an-Nahl; 16:99-100. Bákan náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún fi rinlẹ̀ pé ààbò mímọ́ wà fún ìsọ̀kalẹ̀ al-Ƙur’ān, kíké rẹ̀ àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ láti ojú ayé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) títí di òpin ayé, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Hijr; 15:9 àti sūrah Fussilat; 41:41-42. Nítorí náà, Èsù kan kan kò lè rọ́nà ti ọ̀rọ̀ tirẹ̀ bọ inú al-Ƙur’ān. Bákan náà, ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ eléṣù kò tẹnu Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jáde rí nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah an-Najm; 53: 3-4. Síwájú sí i, Èṣù kan kan kò lè rí àwòrán tàbí ohùn Ànábì wa (s.a.w) yá lò yálà lójú oorun tàbí lójú ayé nítorí hadīth Sọhīh, ní ibi tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti sọ pé “Èṣù kò lè gbé àwòrán mi wọ̀.” Kódà “ƙọrīn” èṣù àlùjọ̀nnú alábàárìn tí Allāhu fi sára ènìyàn kọ̀ọ̀kan, láì yọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan sílẹ̀, tí ó máa ń pa ènìyàn láṣẹ aburú nínú ẹ̀mí, òun gan-an kò lè pa Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láṣẹ aburú nítorí pé Allāhu ṣe àrànṣe fún Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí rẹ̀. Àlùjọ̀nnú náà sì gba ’Islām, kò sì pa Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láṣẹ aburú. Nítorí náà, “ma‘sūm” ẹni tí ààbò mímọ́ wà fún ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tààrà wọ̀nyẹn, mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo kò níí pẹ̀lú ọ̀bọ jẹko láti sọ pé èṣù kan gba ẹnu Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ̀rọ̀ láti sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.”
Ní ti àwọn hadīth tí wọ́n fi gbe ọ̀rọ̀ burúkú náà lẹ́sẹ̀, gbogbo àwọn hadīth náà l’ó lẹ, tí kò ṣe é fi ṣe ẹ̀rí àfi hadīth ẹyọ kan péré. Ìyẹn ni pé, gbogbo hadīth t’ó ń sọ nípa pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.” jẹ́ hadīth t’ó lẹ pátápátá. Àmọ́ èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú wọn kò tayọ èyí tí ó wà nínú sọhīhu-l-Bukọ̄riy, lábẹ́ àkọlé ìforíkanlẹ̀ àwọn mùsùlùmí pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ. Láti ọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu), ó sọ pé: “Dájúdájú Ànábì forí kanlẹ̀ níbi āyah ìforíkanlẹ̀ nínú sūrah an-Najm. Àwọn mùsùlùmí, àwọn ọ̀ṣẹbọ, àlùjọ̀nnú àti ènìyàn sì forí kanlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Hadīth nìyí t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kò sì sí ọ̀rọ̀ “àwọn ẹyẹ àgbà” kan nínú rẹ̀. Ohun tí ènìyàn yó kàn fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ ni pé, kí ló mú àwọn ọ̀ṣẹbọ forí kanlẹ̀ láì tí ì gba ’Islām. Ìdí tí àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn fi forí kanlẹ̀ ni pé, wọ́n gbọ́ orúkọ òrìṣà wọn mẹ́ta kan nínú āyah al-Ƙur’ān, ìyẹn nínú sūrah an-Najm; 53:19-20, wọ́n bá lérò pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) náà ń pàtàkì àwọn òrìṣà náà. Inú wọn sì dùn. Wọ́n bá forí kanlẹ̀. Ìforíkanlẹ̀ wọn kò sì wulẹ̀ wúlò fún n̄ǹkan kan. Àmọ́ níkété tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ké sūrah náà síwájú wọ āyah 26. Ara wọn balẹ̀. Wọ́n sì rí i dájú pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ. Ọ̀tọ̀ ni ohun tí àwọn èṣù inú ẹ̀mí wọn gbé jù sínú ọkàn wọn. wọn fúnra wọn ni wọ́n sọ ohun tí àwọn èṣù inú ẹ̀mí wọn gbé jù sínú ẹ̀mí wọn. Àmọ́ nítorí kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa baà banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi sọ ọ́ di ohun mímọ̀ fún un nínú āyah 52 (ìyẹn, nínú sūrah al-Hajj) pé, kò sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ ti irú rẹ̀ kò sẹlẹ̀ sí rí ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Nítorí náà, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fẹ́ pe làákàyè wọn wálé pé, Allāhu kò lọ́wọ́ nínú àwọn orúkọ òrìṣà náà. Àti pé, kò sí ìkápá ìpẹ̀ ṣíṣe fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Āyah 23 sí 26 nínú sūrah an-Najm sì ń jẹ́rìí sí èyí.
Síwájú sí i, mímú tí àwọn tírà tafsīr mú ìṣẹ̀lẹ̀ náà wà láì sọ àwílé jẹ́ àsọọ̀yán àti àsọọ̀tó. Àmọ́ sá, ẹ̀gbàwá Bukọ̄riy ti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Kò sì sí ọ̀rọ̀ “àwọn ẹyẹ àgbà mẹ́ta” kan kan nínú rẹ̀. Nítorí náà, hadīth kò báà lé ní igba lórí ọ̀rọ̀ kan náà, tí ó bá ti tako āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí tí ó bá tako hadīth Bukọ̄riy tàbí hadīth Muslim, irú hadīth náà kò wúlò nínú ẹ̀sìn wa láti fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀.


الصفحة التالية
Icon