Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà.
____________________
Gbólóhùn yìí “Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò.” Ìyẹn nínú ’Islām tí Allāhu fi rán Òjíṣẹ́ wọn sí wọn nítorí pé, ’Islām ni ẹ̀sìn fún gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjísẹ́ Olọ́hun, àmọ́ ìlànà ìjọ́sìn kan láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn lè yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ìjọ Òjíṣẹ́ kan tí kò ní ìrun tirẹ̀, àmọ́ òǹkà rakaa àti àsìkò ìrun ń yàtọ̀ láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn. Bákan náà ni ìyàtọ̀ tún lè wà nínú ìṣe àti àṣà láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn. Bí àpẹẹrẹ, àṣà ìkúnlẹ̀-kíni jẹ́ ìṣe ẹ̀tọ́ nínú ìjọ ìṣaájú, àmọ́ ó jẹ́ ìṣe èèwọ̀ nínú ìjọ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo ìjọ Òjíṣẹ́ ni wọ́n lè yàtọ̀ síra wọn ní ojú pọ̀n-nà wọ̀nyẹn, àmọ́ kò sí ìyàtọ̀ láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn lórí jíjẹ́ tí Allāhu ń jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Ọlọ́hun, Olúwa àti Olùgbàlà àti ṣíṣe ẹbọ ní èèwọ̀. Èyí gan-an ni ìpìlẹ̀ fún ìgbàgbọ́ òdodo tí gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun mú wá.