Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.
____________________
Ọ̀kan pàtàkì nínú ẹ̀rí t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò fi ẹ̀sìn kristiẹniti tàbí ẹ̀sìn yẹhudi rán Òjíṣẹ́ kan kan rí ni gbólóhùn “(Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí”. Gbólóhùn náà ti fi hàn kedere pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) t’Ó fi ẹ̀sìn kan ṣoṣo rán gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w.), Òun l’Ó sọ ẹ̀sìn náà ni ’Islām. Ó sì sọ ẹlẹ́sìn náà ni “mùsùlùmí”. Tí ẹnì kan bá pe ara rẹ̀ ní kristiẹni, ẹ bi í léèrè pé “ta ni ó sọ ẹ̀sìn kan ní kristiẹniti? Ta sì ni ó sọ ọ́ ní kristiẹni?” Ó dájú pé kì í ṣe Allāhu, Ọlọ́hun (subhānahu wa ta'ālā). Ọpẹ́ ni fún Allāhu tí Ó tọ́ wa sọ́nà tààrà Rẹ̀, ’Islām.


الصفحة التالية
Icon