Onísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin. A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
____________________
N̄ǹkan mẹ́ta ni kalmọh “nikāh” dúró fún. Ìkíní, “ ‘aƙdu-nnikāh”; ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ìtakókó yìgì”. Èyí ni kí waliyyu (aláṣẹ) obìnrin sọ fún ọkùnrin kan pé, “Mo fi ọmọbìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ lágbájá fún ọ, kí o fi ṣe ìyàwó.” Gbólóhùn yìí lè wáyé yálà nípasẹ̀ kí ọkùnrin náà bèèrè fún un pé, “Ẹ fún mi ní ọmọbìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ lágbájá kí n̄g fi ṣe ìyàwó.” (ìyẹn síwájú gbólóhùn waliyyu obìnrin náà) tàbí kí ọkùnrin náà sọ pé, “Mo tẹ́wọ́ gbà á láti fi ṣe ìyàwó” (ìyẹn lẹ́yìn gbólóhùn waliyyu). Gbólóhùn ti waliyyu àti gbólóhùn ti ọkùnrin náà ni a mọ̀ sí “gbólóhùn ìtakókó yìgì. Ìkejì, “nikāh” tún túmọ̀ sí “jimọ̄‘”; ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “oorun ìfẹ́” èyí tí ó (ń) wáyé lẹ́yìn “ ‘aƙdu-nnikāh” – ìtakókó yìgì. Ìkẹta, “nikāh” tún túmọ̀ sí àdàpè àgbèrè “zinā”. Oríkì “zina” nìyí: “Kí ọkùnrin kan ṣe jimọ̄’ (oorun ìfẹ́ lójú ara) obìnrin kan ṣíwájú “aƙdu-nnikāh” láì sí nínú ìrújú lórí irú ẹni tí obìnrin náà jẹ́.” Zina yìí l’ó ń bí ìjìyà kòbókò ọgọ́rùn-ún fún ẹni tí kò ì ṣe “ ‘aƙdu-nnikāh” pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Ó sì ń bí lílẹ̀ lókòpa fún ẹni tí ó bá ti ṣe “ ‘akd-nnikāh pẹ̀lú ẹnì kan rí ṣíwájú. Nikāh tí ó ń túmọ̀ sí “zinā” yìi sì ni ìtúmọ̀ t’ó wà fún kalmọh “nikāh” t’ó jẹyọ nínú āyah yìí. Nípa èyí, àgbọ́yé āyah náà ni pé, alágbèrè lọ́kùnrin kò lè rí obìnrin kan mú ní ọ̀rẹ́ oníṣekúṣe bí kò ṣe alágbèrè ẹgbẹ́ rẹ̀ lóbìnrin tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin tí kò mọ zinā sí èèwọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni pé, alágbèrè lóbìnrin kò lè rí ọkùnrin kan mú ní ọ̀rẹ́ alágbèrè, bí kò ṣe alágbèrè ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin tí kò mọ zinā sí èèwọ̀. Āyah yìí kò ṣe ní èèwọ̀ fún onígbàgbọ́ òdodo láti ṣe ‘aƙdu-nikāh (ìtakókó yìgì), lẹ́yìn náà jimọ̄‘ (oorun ìfẹ́) pẹ̀lú ẹni tí ó ti ronú pìwàdà lórí zinā. Zinā ni Allāhu sì ń tọ́ka sí pé Òun ṣe ní èèwọ̀ ní ìparí āyah náà, kì í ṣe ṣíṣe ‘aƙdu-nikāh pẹ̀lú ẹni t’ó ti ronú pìwàdà lórí zinā.