Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan.
____________________
Āyah yìí ti fi rinlẹ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìlú ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti gbé Òjíṣẹ́ dìde. Bí àpẹẹrẹ, kò sí Òjíṣẹ́ Allāhu t’ó jẹ́ Yorùbá, Haúsá tàbí Ibò. Àmọ́ ní ti sūrah Fātir; 35:24 kò sí ìjọ kan tí Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ si. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, “ummah” dúró fún àpapọ̀ ìjọ ènìyàn fún àkókò Òjíṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Òjíṣẹ́ Allāhu fún àpapọ̀ ìjọ ènìyàn, yálà funfun tàbí dúdú, láti àsìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti gbé e dìde ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀ títí di òpin ayé.