Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.
____________________
Ìṣẹ̀dá ènìyàn wáyé nípasẹ̀ oríṣi ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkíní; nípasẹ̀ erùpẹ̀. Èyí sì ni Allähu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá bàbá wa àkọ́kọ́, Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń ki ìṣẹ̀dá wa mọ́ erùpẹ̀ nítorí ti Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìkejì; nípasẹ̀ ẹfọ́nhà. Èyí sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá ìyá wa àkọ́kọ́, Hawā’ (r.ah). Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń kí ìṣẹ̀dá àwọn obìnrin mọ́ àwa ọkùnrin, nítorí ti Hawā’ ni (rọdiyallāhu 'anhā). Ìkẹta; nípasẹ̀ omi àtọ̀. Èyí si ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá èmi àti ẹ̀yin. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń ki ìṣẹ̀dá wa mọ́ omi nítorí ti èmi àti ẹ̀yin ni. Ìkẹrin; nípasẹ̀ atẹ́gùn ẹ̀mí àti gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀. Èyí sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kíyè sí i! Àti ìkíní àti ìkejì àti ìkẹta, kò sí ènìyàn kan tí kò ní atẹ́gùn ẹ̀mí lára ṣíwájú kí ó tó di abẹ̀mí. Ṣebí atẹ́gùn ẹ̀mí tí Allāhu ṣẹ̀ṣẹ̀ fi rán mọlāika Jibril ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sí Mọryam, ìyá Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni Allāhu fúnra Rẹ̀ fẹ́ sínú ọbọrọgidi Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa àti olùgbàlà. Báwo ni Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) yó ṣe wá jẹ́ olúwa àti olùgbàlà! Kò sì sí ènìyàn kan tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ni sọ gbólóhùn “kunfayakūn” fún, ṣíwájú kí ó tó máa bẹ.