Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
____________________
Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti àkọ́bí rẹ̀, Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) dé ìlú Mọkkah ṣíwájú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àmọ́ kì í ṣe pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí ará ìlú Mọkkah. Bẹ́ẹ̀ náà ni èyíkéyìí Ànábì Ọlọ́hun tí ìtàn bá sọ nípa rẹ̀ pé ó dé ìlú Mọkkah tàbí ìlú mìíràn nínú àwọn ìlú Lárúbáwá. Ó lè dé ibẹ̀ rí, àmọ́ tí Allāhu kò sì níí rán an níṣẹ́ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ànábì ‘Ismā‘īl gan-an ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tí wọ́n gbé wá wò láti òpóǹló nínú ìlú Mọkkah, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò kúkú rán an níṣẹ́ sí ìran Lárúbáwá ní àpapọ̀ tàbí sí ìlú kan nínú ìlú àwọn Lárúbáwá. Àmọ́ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán an níṣẹ́ sí ọ̀wọ́ ẹbí rẹ̀ nínú ìdílé ìyàwó rẹ̀ t’ó jẹ́ Lárúbáwá. Ìyẹn sì ni àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Mọryam; 19:54-55.
Bákan náà, tòhun ti bí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n fún ní tírà Taorāt, iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ kò kúkú kan àwọn ènìyàn Kidr (rọdiyallāhu 'anhu). Kódà Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ìbá tí mọ̀ pé àwọn ènìyàn kan tún wà ní àyè mìíràn lábẹ́ Kidr tí kò bá jẹ́ pé Allāhu pa á láṣẹ láti ṣàbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wàyí bí a ṣe rí àwọn āyah kan t’ó ń fi rinlẹ̀ pé kò sí ìjọ tí Allāhu kò rán Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan sí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:7, sūrah an-Nahl; 16:36 àti sūrah Fātir; 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:46, sūrah Saba’; 34:44, sūrah as-Sajdah; 32:3 àti sūrah Yāsīn; 36:6.)
Ẹ rántí àlàyé tí mo mú wá lórí iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ’Isma‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Lẹ́yìn náà, àgbọ́yé t’ó wà nínú àwọn āyah t’ó wá lórí àìsí Òjíṣẹ́ fún àwọn Lárúbáwá ni pé, kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan, àti pé àwọn méjèèjì ni wọ́n mọ Ilé Kaaba ga sókè, àwọn ìran Lárúbáwá tún ní àǹfààní láti rìn kan àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. Nípasẹ̀ èyí, wọ́n tún gbúròó gbọ́ nípa òǹkà púpọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ ọmọ ’Isrọ̄’īl, ní pàtàkì jùlọ nípa Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kì í ṣe pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ Ànábì Lárúbáwá. Paríparí rẹ̀ ni pé, ìgbà pípẹ́ gbọọrọ tún wà láààrin ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gun sánmọ̀ lọ láàyè àti ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ìkẹ́yìn dìde, ìyẹn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:19. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn fi sọ pé, irúfẹ́ àwọn ènìyàn t’o ṣẹ̀mí láààrin ìgbà náà ni wọ́n ń pè ní “’ahlu-l-fatrah”. Ọjọ́ Àjíǹde sì ni Allāhu máa tó yanjú ọ̀rọ̀ wọn. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú nímọ̀ nípa ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ àti ẹni tí kò níí tẹ̀lé e nínú wọn bí Ó bá jẹ́ pé Allāhu tètè rán Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí wọn. Àpẹẹrẹ wọn tún ni àwọn ọmọdé t’ó kú ṣíwájú bíbàlágà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti nímọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá dágbà. Èyí ni òdodo ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ àwọn “’ahlu-l-fatrah”, ìyẹn àwọn t’ó ti kú ṣíwájú iṣẹ́ jíjẹ́ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn ènìyàn mìíràn t’ó ti kú ṣíwájú tiwọn àti ṣíwájú kí Allāhu tó gbé Ànábì dìde fún wọn.
Kíyè sí i, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fi àdámọ́ òye àtinúwá sára gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ láti jìnnà sí jíjọ̀sìn fún òrìṣà nítorí gbogbo ẹ̀dá l’ó ní òye pé kì í ṣe òrìṣà ni ẹlẹ́dàá àwọn, àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu, Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan t’ó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé, dípò kí ó jẹ́ Ànábì fún ìran Lárúbáwá nìkan gẹ́gẹ́ bí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì t’ó ṣíwájú rẹ̀ ṣe jẹ́, ńṣe ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú ọlá Rẹ̀ ṣe é ni Ànábì gbogbo ayé pátápátá. Allāhu tí Ó ṣe ìṣẹ̀dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ àìlo àtọ̀ ọkùnrin kan kan fún ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ìyàtọ̀ sí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ̀, Òun náà (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó kúkú ṣe Ànábì Muhammad ní Òjíṣẹ́ gbogbo ayé, tí kò sì sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ rí fún ṣíwájú rẹ̀. Nítorí náà, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Ànábì àti Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́ fún ẹbí rẹ̀ àti ìran rẹ̀, ìran Lárúbáwá, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ìkẹ́yìn fún àpapọ̀ Lárúbáwá àti àwọn elédè mìíràn pátápátá.


الصفحة التالية
Icon