Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
____________________
"Hidāyah" túmọ̀ sí ìwọ̀nyí: (1) Ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn ’Islām, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú àdúà nínú sūrah al-Fātihah; 1:6. (2) Ṣíṣí ọkàn ẹ̀dá payá fún gbígba ẹ̀sìn ’Islām. Kò sí èyí lọ́wọ́ ẹnì kan àfi Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nítorí pé, ọwọ́ Rẹ̀ ni ọkàn ẹ̀dá wà. Hidayah t’ó ń túmọ̀ sí ìṣípayá ọkàn fún gbígbà ẹ̀sìn ’Islām l’ó jẹyọ ní àyè yìí, ìyẹn sūrah al-Ƙọs̱ọs̱; 28:56 àti nínú sūrah al-Hajj; 22:24 pẹ̀lú sūrah az-Zukruf; 43:40. (3) Fífi al-Ƙur’ān àti sunnah ṣàlàyé ìmọ̀nà sí ọ̀nà tààrà ’Islām, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52. (4) Títọ́ka ènìyàn sí ibì kan tàbí fífi ojú-ọ̀nà kan mọ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú sūrah as-Sọffāt; 37:23. Nítorí náà, kókó ọ̀rọ́ ni pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ olùtọ́ni-sọ́nà pẹ̀lú al-Ƙur’ān àti sunnah rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá, ṣùgbọ́n Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Olùtọ́ni-sọ́nà pẹ̀lú ìṣípayá-ọkàn fún ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́ nítorí pé, àdéhùn Rẹ̀ ni pé, igun kan fún Ọgbà Ìdẹ̀ra, igun kan fún Ọgbà Iná.


الصفحة التالية
Icon