Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé, níwọ̀n ìgbà tí āyah 52 àti 53 òkè yìí ti fi rinlẹ̀ pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè bá òkú sọ̀rọ̀ kí ó gbọ́, kí ó sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jí òkú dìde; níwọ̀n ìgbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè la etí adití kí ó gbọ́rọ̀ àti níwọ̀n ìgbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè la ojú afọ́jú kí ó ríran gẹ́gẹ́ bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe la ojú afọ́jú, wọ́n ní nígbà náà kí l’ó fẹ́ sọ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) di aṣíwájú bíi ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àti pé, kò lè sí ìgbàlà lọ́dọ̀ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí pé, kò lè jí òkú dìde, kò lè la etí adití, kò sì lè la ojú afọ́jú. Wọ́n ní nítorí náà, ọ̀dọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ni ìgbàlà wà nítorí pé, ó ṣe gbogbo ìwọ̀nyẹn àti òmíràn fún ará ayé!
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, iṣẹ́ ìyanu kọ́ ni òṣùwọ̀n fún ta ni ó lè jẹ́ aṣíwájú àwọn ènìyàn. Ẹnì kan kan kò sì lè rọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan lóyè nípasẹ̀ àìṣe iṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan t’ó dá iṣẹ́ ìyanu ṣe láti ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ bí kò ṣe èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá yọ̀ǹda fún un láti ṣe nítorí pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan tí Allāhu kò fún ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe ní ìbámu sí ìgbà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni èyíkéyìí iṣẹ́ ìyanu tí ó bá tọwọ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan wáyé kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ náà di olúwa àti olùgbàlà. Allāhu nìkan ṣoṣo ní Olúwa àti Olùgbàlà ayé àti ọ̀run. Nítorí náà, fún àlékún lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mọ̄’idah; 5:110.
Lẹ́yìn náà, kì í ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ní agbára láti fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní irúfẹ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu òkè wọ̀nyẹn ṣe, tí Allāhu bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ àwọn kristiẹni, gẹ́gẹ́ bí ìṣesí wọn, ńṣe ni wọ́n gbé àwọn āyah náà ka ibùgbékà òdì nítorí pé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ṣíṣe ni àkòrí àwọn āyah náà bí kò ṣe pé àpẹẹrẹ àti àpèjúwe àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ni kókó nínú àwọn āyah náà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà wé òkú, adití àti afọ́jú ni. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi yé Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé, lẹ́yìn tí ó bá ti ké àwọn āyah fún àwọn ènìyàn nípa òdodo ’Islām, ẹni tí ó bá tún takú sórí àìgbàgbọ́, kì í ṣe ènìyàn t’ó pé níye mọ́, onítọ̀ún ti wà nípò òkú, ẹni tí kò lè ṣe àtúnṣe kan kan mọ́ sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ti wà nípò adití nítorí pé, adití kì í gbọ́rọ̀. Bákan náà, aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ti wà nípò afọ́jú nítorí pé, afọ́jú kì í ríran, kò sì lè dárìn láì níí máa já sí kòtò àti gelemọ. Nítorí náà, àfiwé àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ní kókó àti àkòrí àwọn āyah náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu.
Lẹ́yìn náà, irúfẹ́ àwọn āyah náà ń pa ìbànújẹ́ rẹ́ nínú ọkàn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni nítorí pé, bí ó ṣe ń wù ú tó àti bí ó ṣe ń jẹ̀rankàn tó ni pé, kí gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ gbàgbọ́ nínú Allāhu. Àmọ́ wọn kò gbàgbọ́, Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ń pàrọwà fún un pé, ọwọ́ Òun ni ìyẹn wà. Kí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) má wulẹ̀ fi ìrònú ìyẹn han ara rẹ̀ léèmọ̀.


الصفحة التالية
Icon