Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A fi tì yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.”
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé àwọn āyah t’ó ń sọ nípa ẹ̀mí gbígbà tàbí ikú takora wọn nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n ní àwọn āyah náà ni: sūrah az-Zumọr; 39:42, sūrah al-’Anfāl; 8:50, sūrah al-’Ani‘ām; 6:61 àti sūrah as-Sajdah; 32:11.
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu ni Ẹlẹ́dàá ìṣẹ̀mí àti ikú, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ìṣẹ̀mí wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Kò sì sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ikú wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nípa èyí, Allāhu l’Ó ń fi àṣẹ Rẹ̀ gba ẹ̀mí kúrò lára ẹ̀dá Rẹ̀ ní àkókò tí Ó ti kọ mọ́ ọn nínú kádàrá. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Bákan náà, Allāhu ṣẹ̀dá àwọn mọlāika gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti òjíṣẹ́ Rẹ̀ lórí gbogbo n̄ǹkan. Nípa èyí, àwọn mọlāika kan wà fún ẹ̀mí gbígbà. Ìyẹn l’ó jẹyọ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:50 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:61. Allāhu sì fi ẹnì kan ṣe ọ̀gá nínú àwọn mọlāika t’ó wà níbi ẹ̀mí gbígbà. Ọ̀gá yìí l’ó sì gbé orúkọ àti àwòrán ikú rù. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah as-Sajdah; 32:11. Níbo wá ni ìtakora wà? Kò sí. Al-hamdulillah.