(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Ìtúmọ̀ “Ànábì” ni olùgba-wáhàyí, arímìsíígbà tàbí onímìísí. Ìmísí yìí náà sì ni ó máa fi jíṣẹ́ fún àwọn ìjọ rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé, kò sí ẹni tí ó lè di Òjíṣẹ́ Allāhu (afìmísíjíṣẹ́) àfi kí ó kọ́kọ́ jẹ́ Ànábì (arímìsíígbà). Ìmísí mímọ́ náà ni ó máa jẹ́ òfin ẹ̀sìn fún onímìísí náà àti ìjọ rẹ̀. Fún wí pé Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni “kātamu-nnabiyyīn” òpin àwọn arímìsíígbà, kò lè sí afìmísíjíṣẹ́ kan kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìtúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” nìyí nínú ẹ̀gbàwá Jubaer ọmọ Mut‘im, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hi, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim). Kíyè sí i, àwọn kan bíi ijọ Ahmadiyyah kò gbàgbọ́ pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n kọ́kọ́ fún “kātamu-nnabiyyīn” ní ìtúmọ̀ t’ó yàtọ̀ sí èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú āyah náà. Wọ́n ní “òrùka àwọn Ànábì” ni ìtúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn”. Lẹ́yìn náà, ìjọ Ahmadiyyah sọ pé, “Ànábì àti Òjíṣẹ́ Allāhu tí ó dìde nínú ìlú Ƙọ̄diyan, nílẹ̀ India tún ni olùdásílẹ́ ìjọ Ahmadiyyah, mirza ghulam Ahmad.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún ni Imam Mahdi tí à ń retí lópin ayé.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún ni Mọsīh, ‘Īsā ọmọ Mọryam tí à ń retí lópin ayé.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún sọ àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú ìjọ rẹ̀ di ànábì.”
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, fúnra Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn Sọhābah (r.ahm) l’ó túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí “òpin àwọn Ànábì”. Ìṣìnà pọ́nńbélé ni fún ẹnikẹ́ni láti túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí n̄ǹkan mìíràn. “Òpin àwọn Ànábì” sì ni gbogbo tírà Tafsīr túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí. Kò sì sí ìyapa-ẹnu láààrin gbogbo àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām lórí títúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí “òpin àwọn Ànábì”. Dandan sì ni kí á gbógun ti ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa ìpanupọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām.
Lẹ́yìn náà, ní ti arákùnrin tí wọ́n ń pè ní mirza ghulam Ahmad, òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn wulẹ̀ ni òun. Irọ́ ẹnu rẹ̀ ti pọ̀ jù. Alágbárí pọ́nńbélé sì ni pẹ̀lú. Irú iṣẹ́ aburú tí ṣeeu Ahmada Tijāni ṣe fún ’Islām gẹ́lẹ́ náà ni mirza ghulam Ahmad ṣe. Àwọn méjèèjì ni Pọ́ọ̀lù láààrin àwa mùsùlùmí. Ẹ wo díẹ̀ nínú irọ́ ńlá rẹ̀. Mirza ghulam Ahmad sọ pé: "Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé, bí ọmọ Mi ló ṣe wà sí Mi." (Tadhkirah, 362) Ṣé Allāhu bímọ ni? Ṣebí àwọn kristiẹni l’ó ń parọ́ mọ Ọlọ́hun pé Ó bímọ, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò bímọ, kò sì sọ ẹnì kan kan di ọmọ Rẹ̀. Irọ́ mìíràn nìyí láti ẹnu mirza ghulām Ahmad, ó sọ pé: "Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé, ìwọ wá láti ara Mi; Èmi náà wá láti ara rẹ." (Tadhkirah, ojú ewé 295) Ṣebí àwọn kristiẹni l’ó máa ń sọ pé ọlọ́hun t’ó wá láwòrán ọmọ ni Jésù Kristi! Ṣé ẹ̀ ń rí ìjọra láààrin ìjọ Ahmadiyyah àti àwọn kristiẹni báyìí. Irọ́ mìíràn nìyí láti ẹnu mirza ghulām Ahmad, ó sọ pé: "Nínú ìríran ẹ̀mí, mo rí ara mi pé èmi gan-an ni Allāhu. Mo sì ní ìgbàgbọ́ pé èmi gan-an nìyẹn." (Tadhkirah, 118) Ẹ wo bí ó ṣe sọra rẹ̀ di ọlọ́hun! Lẹ́yìn náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:158 kí ẹ rí bí ó ṣe sọra rẹ̀ di Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún òun àti ìjọ rẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Àti òun àti ṣeeu Ahmada Tijāniy, wọ́n wáyé láti wá tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ní ọ̀nà ẹkọrọ lórúkọ ’Islām.
Síwájú sí i, àwọn kan tún sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun, kò yẹ fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti padà wá sáyé mọ́ lópin ayé.” Wọ́n tún sọ pé, “Ìgbàgbọ́ àwọn kristiẹni lásán ni ìgbàgbọ́ nínú ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Kì í ṣe ìgbàgbọ́ ’Islām rárá.”
Èsì: Ní ti àwọn wọ̀nyí, wọ́n gbà pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun, àmọ́ ìṣòro tiwọn ni pé, wọn kò gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nípò ẹni tí kò ì kú, wọn kò sì gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń padà bọ̀ lópin ayé. Ọ̀gá ìṣòro àwọn wọ̀nyí ni pé, wọ́n wọ́gi lé gbogbo hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú Bukọ̄riy àti Muslim lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Àwọn hadith náà sì pọ̀ púpọ̀, wọ́n fẹsẹ̀ rinlẹ̀, wọn kò sì ní pọ́n-na rárá. Àmọ́ èrò-ọkàn àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn ni pé, àwọn hadīth náà tako āyah tí àwọn ń túmọ̀ sí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ẹ wo bí wọ́n ṣe ń tinú wàhálà kan bọ́ sínú wàhálà mìíràn lórí ọ̀rọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àdánwò kúkú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí Allāhu kó wa yọ. Àmọ́ sá, ẹ lọ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:55 àti sūrah an-Nisā’; 4:157 kí ẹ lè rí àlàyé apayànjẹ lórí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò ì kú, ó wà ní àyè, ó sì ń padà bọ̀ lópin ayé.