Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn tí A ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ (nìkan l’o lè kọ̀ sílẹ̀ nínú àwọn ìyàwó rẹ). Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Āyah yìí kò ní kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) má ṣe fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní àsìkò tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀, ṣùgbọ́n āyah yìí kọ̀ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti yọ èyíkéyìí ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ipò ìyá àwọn onígbàgbọ́ òdodo nípasẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ àfi ìyàwó tí ó bá jẹ́ ẹrú ogun ní ìpìlẹ̀. Ìyá wa ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā) sọ pé: “Òjíṣẹ́ Allāhu kò tí ì kú títí Allāhu fi ṣe àwọn obìnrin ayé ní ẹ̀tọ́ fún un láti fẹ́.” Ìyẹn ni pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fẹ́ ìyàwó lọ́ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Kíyè sí i, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kọ ìyá wa Hafsọh ọmọ ‘Umar sílẹ̀, lẹ́yìn náà ó fẹ́ ẹ padà. Bákan náà, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbèrò láti kọ ìyá wa Saodah sílẹ̀. Èyí sì ni ó ṣokùnfà tí Saodah (rọdiyallāhu 'anhā) fi yọ̀ǹda ọjọ́ tirẹ̀ fún ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā). Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ āyah yìí. (at-Tọbariy). Nítorí náà, kí Ànábì fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ láì ní ẹnu àlà, láì sì gbọdọ̀ tìtorí èyí kọ ọ̀kan sílẹ̀, àfi ẹrú ogun, èyí tún jẹ́ n̄ǹkan ẹ̀ṣà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣà á lẹ́ṣà. Ìdí ni pé, òǹkà ìyàwó mùsùlùmí kò gbọdọ̀ tayọ mẹ́rin ní abẹ́ àkóṣo rẹ̀. Tí òǹkà ìyàwó Mùsùlùmí bá sì pé mẹ́rin, mùsùlùmí lè kọ ọ̀kan sílẹ̀ láti lè fi òmíràn jìrọ̀ rẹ̀, ìyẹn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ wo sūrah an-Nisā’;4:3 àti 20-21.