(Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. A sì sọ wọ́n di ìtàn. A sì fọ́n wọn ká pátápátá. Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
____________________
Ọ̀kan nínú oore tí Allāhu (s..w.t.) ṣe fún àwọn ará Saba’ ni pé, Ó fi àwọn ìlú t’ó já mọ́ra wọn yí wọn ká. Wọ́n sì ń rí oore púpọ̀ láti ara àwọn onírìn-àjò t’ó ń gba ìlú wọn kọjá. Àmọ́ wọn kò mọ ìwọ̀nyí sí oore. Wọ́n jọra wọn lójú, wọ́n sì tọrọ pé kí Allāhu taari àwọn ìlú náà kúrò nítòsí àwọn. Allāhu sì taari àwọn fúnra wọn dànù. Allāhu fi adágún odò tú ìlú wọn ká. Wọ́n sì fọ́nká káàkiri ayé.


الصفحة التالية
Icon