Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ olúwa) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn.


الصفحة التالية
Icon