Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, wọ́n á wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá yín ń jọ́sìn fún.” Wọ́n tún wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́.” Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí nípa òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”