Sọ pé: “Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá.”
____________________
Okùnfà āyah yìí ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah ń sọ fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé, “Tí o bá fi lè pa ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà àwọn bàbá rẹ tì, o ti ṣìnà nìyẹn.” Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ āyah kalẹ̀ pé, kí ó fún wọn lésì pé “Ti mo bá ṣìnà gẹ́gẹ́ bí ẹ ti sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́, ìyà ìṣìnà mi kò kàn yín. Àmọ́ tí mo bá mọ̀nà nípasẹ̀ bí mo ṣe ń jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo, ìmọ̀nà mi wáyé nípasẹ̀ ìmísí tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí mi ni. Kì í ṣe àdáṣe mi.” Ƙurtubiy