Òru jẹ́ àmì kan fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).
____________________
Kókó inú āyah yìí ni pé, òru l’ó ń ṣíwájú ọ̀sán nínú ọjọ́, bí àpẹẹrẹ, òru Jímọ̀ mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Nítorí náà, kò sí òru Àlàmísì mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Bákan náà, wíwọ̀ òòrùn ni ìparí ọjọ́ kan àti ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ mìíràn. Ìyẹn ni pé, níkété tí òòrùn bá ti wọ̀, a ti parí ọjọ́ tí à ń lò bọ̀, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ titun. Ní ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, ni ọjọ́ kan ń parí, tí ọjọ́ titun ń bẹ̀rẹ̀ ní aago méjìlá òru. Ìyẹn kì í ṣe ìlànà ti Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Síwájú sí i, tí obìnrin bá bímọ, ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìparan súná ọmọ náà. Báwo ni a ó ṣe ka ọjọ́ méje náà? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn kan lérò pé, ọjọ́ mẹ́jọ ni ọjọ́ súná ọmọ. Èyí sì tako hadīth súná ọmọ ṣíṣe tí Samrah ọmọ Jundub (rọdiyallāhu 'anhu) gbà wá pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: كُلُّ غُلاَمٍ رَهِينَةٌ بِعَقِيقَتِهِ تُذْبَحُ عَنْهُ يَوْمَ سَابِعِهِ وَيُحْلَقُ وَيُسَمَّى Ìtúmọ̀: “Ọmọ titun kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ti fi ẹran ‘aƙīkọh kan dógò fún tí wọ́n máa bá a pa ní ọjọ́ keje rẹ̀ (t’ó dáyé). Wọ́n máa fá irun orí rẹ̀. Wọ́n sì máa fún un ní orúkọ.” (Abu Dāud) Irú ẹ̀gbàwá yìí wà nínú An-Nasā’iy, Ahmad àti Baehaƙiy.
Àṣìṣe tí àwọn ọlọ́jọ́ mẹ́jọ fún súná ọmọ ṣíṣe ṣe ni pé, wọn kì í ka ọjọ́ ìbímọ mọ́ ọn. Dandan sì ni kí ọjọ́ ìbímọ jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọjọ́ méje náà, kódà kí ọjọ́ ìbímọ ku ìṣẹ́jú kan tí a ó fi bọ́ sínú ọjọ́ titun. Bí àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan bá bímọ ní ọ̀sán Alaadi, ní àkókò bíi kó ku ìṣẹ́jú díẹ̀ tí òòrùn máa wọ̀ ní ọjọ́ náà, ọjọ́ Alaadi ni ọjọ́ ìbímọ̀ rẹ̀. Ọjọ́ Sabt l’ó sì máa jẹ́ ọjọ́ keje, tí ó máa jẹ́ ọjọ́ súná ọmọ náà. Ṣebí nínú ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n, tí obìnrin kan bá rí n̄ǹkan oṣù rẹ̀ ní bíi kó ku ìsẹ́jú díẹ̀ tí òòrùn máa wọ̀, ọ́ máa mú ọjọ́ yẹn kà mọ́ iye òǹkà ọjọ́ tí ó máa san padà lẹ́yìn oṣù Rọmọdọ̄n. Nítorí náà, ọjọ́ keje súná ọmọ kò gbọ́dọ̀ di ọjọ́ kẹjọ mọ́ wa lọ́wọ́. Bákan náà, àdádáálẹ́ ni ṣíṣe ìjókòó aláláàfáà fún súná ọmọ ṣíṣe. Súná ọmọ ṣíṣe kò tayọ bí ó ṣe wà nínú hadīth yẹn. Àti pé dandan ni fún òbí láti fá irun orí ọmọ titun náà ní ọjọ́ keje, yálà ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Ọmọ kó gbọ́dọ̀ di dàda nítorí pé irun ọ̀bùn àti irun ẹbọ ni irun dàda.


الصفحة التالية
Icon