Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.
____________________
Kíyè sí i, gbólóhùn yìí, “Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín!” Ìyẹn ṣíwájú kí ó tó kú (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam), kò sí láààrin wa mọ́. Irú āyah yìí wà nínú sūrah at-Taobah; 9:94 àti 105 àti sūrah an-Nisā’; 4:64. Àwọn onibidia nìkan ni wọ́n tún gbà pé títí dí àsìkò yìí ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń bẹ láààrin wa, tí ó ń rí iṣẹ́ ọwọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ìjọ Ahmadiyyah gbà pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) padà wá sáyé, ó sì ń bá mirza Ghulam Ahmad, olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah ṣe ìpàdé ojú ayé. Bákan náà, ìjọ Tijāniyyah náà gbà pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) padà wá sáyé láti fún ṣeeu Ahmada Tijāni lọ́wọ́ wírìdí. Kódà wọ́n gbà pé lójoojúmọ́ àti níbi gbogbo ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn àrólé rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin (r.ahm) máa wá jókòó sórí aṣọ funfun, èyí tí wọ́n máa ń tẹ́ sáààrin lásìkò tí wọ́n bá ń ka Jaoharatul-kamāl lọ́wọ́. Irọ́ ńlá ni gbogbo àdìsọ́kàn burúkú wọ̀nyí. Àwọn āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ kò sì jẹmọ́ “lẹ́yìn ikú Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam)” bí kò ṣe “ṣíwájú ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam)”. Kí á lè mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àmọ̀dájú, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Kíyè sí i, dájúdájú wọn máa mú àwọn ọkùnrin kan wá nínú ìjọ mi (ìyẹn l’ọ́jọ́ Ìdájọ́), wọ́n sì máa mú wọn lọ sí apá òṣì, n̄g ó sì sọ pé; “Olúwa mi, àwọn ènìyàn mi (nìyí).” Wọ́n sì máa sọ pé: “Dájúdájú ìwọ kò mọ ohun tí wọ́n dáálẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ.” (Bukọ̄riy àti Muslim)