(Ànábì Dāwūd) sọ pé: "Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-àlà lórí apá kan àfi àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n. (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni- afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu).
____________________
Kíyè sí i, àwọn ìtàn kan tí àwọn kristiẹni máa ń sọ nípa Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pé gbígbà tí ó gba ìyàwó ẹnì kan nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ mọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyàwó tirẹ̀ l’ó bí ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó jẹyọ nínú āyah yìí. Kódà, àwọn tírà tafsīr kan mú ìtàn náà wá pẹ̀lú láì ṣọ̀fín-tótó rẹ̀. Àwọn olùtọpinpin ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kúkú ti tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì sọ pé, “Ìtàn àwọn ọmọ Isrọ̄’īl lásán ni gbogbo rẹ̀. Ìtàn irọ́ ni. Kódà èyí tí wọ́n ṣàfitì rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú rẹ̀ kò fẹsẹ̀ rinlẹ̀, kò sì ní àlàáfíà.” Tafsīr ’Adwā’ul-bayān ti Ṣinƙītiy l’ó kúkú kó ilà kúrò lára ẹ̀kọ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà sì nìyẹn nítorí pé, kò sí olùgbàyàwó-oníyàwó nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun (a.s.w.). Ní òdodo ni pé, òǹkà ìyàwó wọn lè pọ̀ ní òǹkà, kì í ṣe ní ti ìgbádùn adùn-ara bí kò ṣe pé, wọ́n fẹ́ òǹkà ìyàwó púpọ̀ lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ fún àgbéga ẹ̀sìn ’Islām. Kò sì yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn yẹhudi àti àwọn kristiẹni bá wa lójijì rárá nítorí pé kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan tí wọn kì í tàbùkù.
Síwájú sí i, òye t’ó wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ alábo-ẹran yìí ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹ̀kọ́ ìgbẹ́jọ́ nítorí pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ fi ṣe adájọ́ láààrin àwọn ìjọ rẹ̀. Àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn ni àṣíṣe t’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí náà sì ni ohun tí ó tọrọ àforíjìn Ọlọ́hun fún, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìyàwó gbígbà, èyí tí kò ṣẹlẹ̀ nínú āyah náà, tí kò sì ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) rí nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀.