Dájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà).
____________________
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ṣe parọ́ ìyàwó gbígbà mọ́ Ànábì Dā’ūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe parọ́ pé èṣù àlùjànnú kan gba ìjọba lọ́wọ́ Ànábì Sulaemān ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Wọ́n sì sọ pé, èṣù àlùjànnú náà lo ìjọba rẹ̀ fún ogójì ọjọ́ t’ó ṣe dọ́gba sí òǹkà ọjọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Ànábì Sulaemān fi yọ ẹbọ ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Wọ́n ní, nígbà tí ogójì ọjọ́ pé, ni àṣírí èṣù àlùjànnú náà tó tú. Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sì padà sórí àga ìjọba rẹ̀.’ Irọ́ burúkú ni èyí. Ìṣe àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì ni irọ́ pípa mọ́ àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn burúkú yìí wà nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tírà tafsīr nípasẹ̀ àìfura, àwọn ọlọ́fìn-íntótó àti olùtọpinpin nínú àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām ti padà fi rinlẹ̀ pé, irọ́ ni ìtàn náà nítorí pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà tako ààbò mímọ́ t’ó wà fún àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.).
Síwájú sí i, èyí tí àwọn àáfà fi rinlẹ̀ lórí àgbọ́yé āyah náà ni pé, Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ìyàwó t’ó tó ọgọ́rùn-ún lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ (ìyẹn ni pé, Allāhu s.w.t. l’Ó ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún un). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sì fi Allāhu búra ní ọjọ́ kan pé, òun máa súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan àwọn ìyàwó rẹ̀ náà, gbogbo wọn pátápátá, ní alẹ́ ọjọ́ kan nítorí kí ìkọ̀ọ̀kan wọn lè bí ọmọkùnrin jagunjagun kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀sìn Allāhu. Ó búra láti ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó kùnà láti fi kún ìbúra rẹ̀ pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ ọ̀rọ̀ náà di àdánwò fún un nítorí pé, kò sí ìyàwó kan tí ó lóyún nípasẹ̀ oorun-ìfẹ́ alẹ́ ọjọ́ náà àfi ìyàwò kan tí ó bí ààbọ̀ ọmọ, tí wọ́n gbé jù sórí àga ọlá rẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ tí ó rí èyí, ó ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Allāhu. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí pé, “Tí Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá sọ pé, ‘tí Allāhu bá fẹ́’ lásìkò ìbúra rẹ̀ ni, ìbúra rẹ̀ kò níí di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn. Àti pé ọwọ́ rẹ̀ ìbá ba ohun tí ó ń fẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).” Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wà nínú ẹ̀gbàwá Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu). Ó sì wà nínú hadīth Bukọ̄riy (àkọlé: bāb al-’Istithnā’ fi-l-’aemọ̄n) àti Muslim (àkọlé: bāb al-’Istithnā’). Nítorí náà, ààbọ̀ ọmọ tí wọ́n jù sórí àga Sulaemọn ni “jasad” t’ó jẹyọ nínú āyah náà, kì í ṣe àlùjànnú èṣù. Àwọn èṣù kì í gbé àwòrán àwọn Ànábì wọ̀.
Kíyè sí i, nínú ẹ̀rí t’ó dájú t’ó ń fi rinlẹ̀ pé kò sí èṣù àlùjànnú kan tí ó lè gbé àwòrán Ànábì kan kan wọ̀ ni pé, kì í ṣe ara òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni àwọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n wà. Báwo wá ni ó ṣe máa jẹ́ pé, nípasẹ̀ òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ni àwọ̀ rẹ̀ fi máa kúrò lára rẹ̀ sí ara èṣù àlùjànnú nígbà tí Ànábì Sulaemọ̄n kì í ṣe òpìdán? Ànábì Sulaemọ̄n kò sì fi òrùka jọba áḿbọ̀sìbọ́sí pé nígbà tí kò bá sí òrùka rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ l’ó máa fún ẹlòmíìràn ní àyè láti di ọba! Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:102. W-Allāhu ’a‘lam.


الصفحة التالية
Icon