Fi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ. Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà).
____________________
Ní àsìkò tí àìlera wà fún Ànábì ’Ayyūb ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ìyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́ ní ẹ̀ṣẹ̀ kan. Ànábì ’Ayyūb sì fi Allāhu búra pé òun yóò lù ú ní ẹgba ọgọ́rùn-ún lórí àṣìṣe náà tí òun bá gbádùn. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ń pa á láṣẹ pé kí ó mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ, ṣùgbọ́n kí ó mú ìbáwí náà ní fífúyẹ́ nípa dídi igi koríko tútù ọgọ́rùn-ún jọ, kí ó sì fi lu ìyàwó rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan péré. Ìdì igi koríko ọgọ́rùn-ún náà sì ti dúró fún lílu ìyàwó rẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún. Èyí fi rinlẹ̀ pé, a ò gbọdọ̀ fi àpá sí ara ìyàwó wa nípasẹ̀ ìbáwí. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:34.


الصفحة التالية
Icon