Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
____________________
Irú gbólóhùn yìí tún wà nínú sūrah Muhammad; 47:19. Ẹ̀̀ṣẹ̀ wo ni Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dá? Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kì í ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn tàbí olùyapa àṣẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Àmọ́ nítorí pé kì í ṣe mọlāika, kì í sì ṣe ọlọ́hun, ó ṣeé ṣe kí ó ṣe ìṣe kan tí Allāhu máa pè ní ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Irúfẹ́ àwọn ìṣe náà kò tàbùkù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì yọ ọ́ kúrò nípò àwòkọ́ṣe rere fún gbogbo ẹ̀da.
Allāhu kì í kúkú ṣe Ọba alábòsí, Ó ṣàfi hàn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dá.
Àṣìṣe kìíní t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Títú tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú àwọn ẹrú ogun Badr sílẹ̀ dípò pípa wọ́n, ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn nítorí pé, àwọn tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú sílẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rò t’ó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé, àwùjọ mùsùlùmí bùkátà sí owó àti ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrú kan nínú àwọn ẹrú ogun náà, nígbà tí àwọn ẹrú mìíràn rí ìtúsílẹ̀ gbà nípasẹ̀ kíkọ́ àwọn Sọhābah kan ní ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ní òdodo ni pé, ìgbésẹ̀ yìí dára. Àmọ́ Allāhu kà á kún àṣìṣe. Ó sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé pípa wọn lásìkò náà l’ó lóore ju ìtúsílẹ̀ wọn lọ nítorí pé, àìpa wọ́n l’ó padà bí àwọn ogun mìíràn. Ńṣe ni àwọn ọ̀ṣẹbọ náà lọ túnra mú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ogun mìíràn dìde. Wọn ìbá ti pa wọ́n nígbà àkọ́kọ́, ogun ìbá ti dáwọ́ dúró. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:67-71. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì padà yọ̀ǹda ìtúsílẹ̀ ẹrú ogún pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ tàbí ní ọ̀fẹ́ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú sūrah Muhammad; 47:4.
Àṣìṣe kejì t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Àìtètè gbà kí Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu) kọ Zaenab ọmọ Jahṣ (rọdiyallāhu 'anhā) sílẹ̀ lẹ́yìn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé Zaed ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí kò bùkátà sí i mọ́. Ohun tí ó sì mú kí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kóra ró ni pé, ó ń páyà pé àwọn aláìsàn-ọkàn yóò máa sọ pé, ‘Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, ó sì fi ṣaya!’. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu) kì í ṣe ọmọbíbí inú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àti pé kò sí èèwọ̀ nínú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fẹ́ Zaenab ọmọ Jahṣ lẹ́yìn tí Allāhu ti pa á láṣẹ fún un láti fi ṣaya. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Ahzāb; 33:37-38. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ṣẹ́rí padà síbi ohun tí Allāhu yàn fún un.
Àṣìṣe kẹta t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Sísọ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ fún ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ pé òun kò níí fi ẹrúbìnrin rẹ̀ kan ṣaya. Sísọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣìṣe fún un nítorí pé, ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un ni òun fẹ́ ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ láti fi wá ìyọ́nú ìyàwó rẹ̀ kan. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Tahrīm; 66:1.
Àṣìṣe kẹ́rin t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Fífajúro tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fajú ro sí afọ́jú kan tí Allāhu ti ṣípayá ọkàn rẹ̀ fún gbígba ’Islām. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wà pẹ̀lú ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, tí ó ń ṣe wáàsí fún lọ́wọ́ nígbà tí afọ́jú yìí ń sáré bọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ti kó ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ léyà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi fẹ́ kí afọ́jú t’ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé di òun lọ́wọ́. Ṣíṣẹ bẹ́ẹ̀ l’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi ìdí èyí náà múlẹ̀ nínú sūrah ‘Abas; 80:1-11.
Ìwọ̀nyẹn ni àwọn àṣìṣe t’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ́rùn. Kì í ṣe pé Ànábì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn. Tòhun tí bí ó ṣe mọ yìí, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò yé tọrọ àforíjìn lórí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kódà Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè má tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí ìwọ̀nyẹn nígbà ọgọ́rùn-ún lójúmọ́. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó yẹ kí èyí kọ́ èmi àti ẹ̀yin ni pé, a ò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu, Aláforíjìn. Kò sí ohun t’ó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa, irú èyí tí Allāhu ṣe fún Ànábì wa Muhammad yìí (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí Allāhu sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún gbogbo ayé nínú sūrah al-Fath; 48:1-2.
Ìyẹn ni abala èyí t’ó jẹmọ́ àṣìṣe Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́yìn tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣẹrh; 94:3 fún abala kejì, èyí t’ó jẹmọ́ àṣìṣe rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam).