Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin. (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀).
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé āyah yìí tako àwọn āyah t’ó ń fi ọjọ́ mẹ́fà rinlẹ̀ fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Wọ́n ni āyah yìí pè é ní ọjọ́ mẹ́jọ, àwọn āyah yòókù pè é ní ọjọ́ mẹ́fà. Àwọn kristiẹni tún sọ pé, yálà ọjọ́ mẹ́fà tàbí ọjọ́ mẹ́jọ, ìkíní kejì tún tako àwọn āyah kunfayakūn t’ó wà nínú al-Ƙur’ān. Wọ́n ní, “Kò wulẹ̀ yẹ kí Allāhu lo ọjọ́ mẹ́fà tàbí ọjọ́ mẹ́jọ kan kan mọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé Ó ti sọ nínú al-Ƙur’ān pé nígbà tí Òun bá gbèrò láti ṣẹ̀dá n̄ǹkan, gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀-ó-sì-máa-jẹ́-bẹ́ẹ̀” ni Òun máa ń sọ.”
Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni èyí. Kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé ọ̀rọ̀ nìyí. Ní ti òǹkà ọjọ́ fún ìṣẹ̀dá sánmọ̀ àti ilẹ̀, àyè mẹ́jọ ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ní àyè mẹ́rin nínú wọn, ó jẹyọ nínú wọn pé, “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:54, sūrah Yūnus; 10:3, sūrah Hūd; 11:7 àti sūrah al-Hadīd; 57:4. Ní àyè mẹ́ta nínú wọn, ó jẹyọ nínú wọn pé, “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Furƙọ̄n; 25:59, sūrah as-Sajdah; 32:4 àti sūrah Ƙọ̄f; 50:38. Kíyè sí awẹ́ gbólóhùn “àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì”. Ìyẹn ti fi hàn pé, ọjọ́ méjì ni Allāhu lò fún ìṣẹ̀dá sánmọ̀ méje, ọjọ́ méjì fún ìṣẹ̀dá ilẹ̀ méje, ọjọ́ méjì fún ìṣẹ̀da ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì sì ń túmọ̀ sí gbogbo ohun t’ó wà lórí ilẹ̀. Èyí tí já sí pé, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà lórí ilẹ̀ kó ọjọ́ mẹ́rin nínú ọjọ́ mẹ́fà. Àtúpalẹ̀ ìṣírò yìí ni Allāhu fún ara Rẹ̀ fi rinlẹ̀ nínú āyah tí à ń ṣe ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún yìí, sūrah Fussilat 41; 9-10. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ èdè Lárúbáwá àti àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām fi ṣàlàyé āyah 10 pé ọjọ́ mẹ́rin yẹn kó ọjọ́ méjì tí Allāhu dárúkọ nínú āyah 9 sínú. Wọ́n ní àpapọ̀ ọjọ́ ìṣẹ̀dá ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ ni òǹkà ọjọ́ mẹ́rin náà dúró fún, kì í ṣe fún ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ nìkan, gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn àwọn aláìnímọ̀ nípa ìlò èdè Lárúbáwá. Irúfẹ́ ìṣírò yìí l’ó tún jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 àti Fātir; 35:1. Ní ti gbólóhùn “kunfayakūn” tí í ṣe “Jẹ́ bẹ́ẹ̀-ó-sì-máa-jẹ́-bẹ́ẹ̀”, kò rújú rárá pé, Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ t’òhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Allāhu kì í ṣe n̄ǹkan pẹ̀lú ìkánjú. Àti pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí ṣe ìṣe kan tí ó máa mú kí ìtakora ṣẹlẹ̀ láààrin àwọn orúkọ Rẹ̀ t’ó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn Rẹ̀ t’ó ga jùlọ. Ẹ̀dá l’ó lè jẹ́ alágbára-mámèrò, kì í ṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó wà lábẹ́ lílo òǹkà ọjọ́ mẹ́fà fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run.
Ipò tí gbólóhùn “kunfayakūn” wà nínú ìṣẹ̀dá ni ipò ìparí ọ̀rọ̀ àti àṣẹ dídi bíbẹ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn ìkójọ èròjà ìṣẹ̀dá, n̄ǹkan náà kò níí dòhun àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. Àwọn ẹ̀dá tí kò bá sì jẹmọ́ èròjà ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ nípa èròjà ìṣẹ̀dá wọn fún wa, Allāhu l’Ó kúkú nímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, ìkíní kejì kò níí di ẹ̀dá àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”.
Pẹ̀lú àlàyé yìí, ó ń túmọ̀ sí pé, àwọn ẹ̀dá kan di ẹ̀dá pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” nìkan. Àwọn ẹ̀dá kan sì di ẹ̀dá nípasẹ̀ èròjà ìṣẹ̀dá àti gbólóhùn “kunfayakūn”. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀nà tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, gbólóhùn “kunfayakūn” t’ó jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoṣo kò lè sọ Allāhu di olùkánjú. Ìkánjú kì í ṣe ìròyìn rere fún Allāhu. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”, bẹ́ẹ̀ náà l’Ó ṣe gbàròyìn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, èyí tí í ṣe ìdà kejì ìkánjú. Nítorí náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lágbára láti ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run láààrin ohun tí ó kéré jùlọ sí ìṣẹ́jú kan. Bí Ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò kúkú sí ẹni tí Ó lè pè É lẹ́jọ́. Bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá sì lo ọjọ́ mẹ́fà fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àṣẹ “Jẹ́-bẹ́ẹ̀” kò jẹ́ tiRẹ̀. Òun l’Ó kúkú ni gbogbo ìjọba, gbogbo agbára àti gbogbo ògo.