Ohunkóhun tí ẹ bá yapa ẹnu nípa rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà).
____________________
Àgbọ́yé méjì ni gbogbo tafsīr mú wá lórí gbólóhùn yìí “Ohunkóhun tí ẹ bá yapa ẹnu nípa rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu.” Ìkíní ni pé, lẹ́yìn tí Allāhu ti mú ìdájọ́ wá pé ’Islām nìkan ṣoṣo ni ẹ̀sìn àṣelà, àmọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ yapa rẹ̀, kí àwa mùsùlùmí fi wọ́n sílẹ̀ títí di Ọjọ́ àjíǹde tí Allāhu máa fi ìdájọ́ Rẹ̀ mú ìlèrí ìyà Rẹ̀ ṣẹ lórí wọn. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí, āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah t’ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú àwọn āyah t’ó ń pàṣẹ ìgbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó ń gbógun ti àwa mùsùlùmí àti āyah t’ó ń pàṣẹ gbígba owó-orí lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ tí kò gbógun ti àwa mùsùlùmí. Ní àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn, āyah yìí ń pàrọwà sùúrù àti ìfaradà fún èyíkéyìí àwùjọ mùsùlùmí t’ó wà nípò ọ̀lẹ ní orílẹ̀ èdè tí àwọn kèfèrí bá ti ń lo òfin kèfèrí lé wa lórí. Sùúrù náà máa wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ tí ọwọ́ àwa mùsùlùmí yóò ba èkù-idà, tí agbára sì máa jẹ́ ti ’Islām.
Àgbọ́yé kejì ni pé, kí á ṣẹ́rí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyapa-ẹnu bá wáyé lórí wọn sínú al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí, āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah t’ó ń pa wá láṣẹ láti fi al-Ƙur’an àti sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yanjú àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu, gẹ́gẹ́ bí sūrah an-Nisā’; 4:59.
Àṣìgbọ́ l’ó jẹ́ nígbà náà láti lérò pé āyah náà ń pa wá láṣẹ láti má ṣe mú ìdájọ́ wá lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu tí al-Ƙur’ān ti yanjú. Èyí sì máa mú ìtúmọ̀ wíwo ìbàjẹ́ níran lọ́wọ́. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ìbàjẹ́ oníran-ànran àti àdádáálẹ̀ ẹ̀sìn nínú ’Islam sì máa gbòde kanrí láààrin àwọn ẹ̀dá. Àṣẹ wíwo ìbàjẹ́ níran títí dọjọ́ àjíǹde kò sì tọ̀dọ̀ Allāhu (s.a.w.t) wá nínú tírà sánmọ̀ kan kan.


الصفحة التالية
Icon