Ìyẹn ni èyí tí Allāhu fi ń ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Sọ pé: "Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ bí kò ṣe ìfẹ́ ẹbí.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe rere kan, A máa ṣe àlékún rere fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.
____________________
Ìyẹn ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń sọ fún àwọn ẹbí rẹ̀ pé, ẹ má ṣe tìtorí pé mò ń pèyín sínú ẹ̀sìn ’Islām kí ẹ wá máa fi ìnira kan èmi àti àwọn ará ilé mi. Èmi kò kúkú bèèrè owó-ọ̀yà kan kan lọ́wọ́ yín. Ẹ sì mọ̀ pé ẹbí ni wá. Ẹbí sì gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ ẹbí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi fífi ìnira kan ará ilé mi ṣe ẹ̀san fún mi.


الصفحة التالية
Icon