Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàmójúkúrò, tí ó tún ṣàtúnṣe, ẹ̀san rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.
____________________
Kíyè sí i, gbólóhùn yìí “Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀.” kò tako sūrah Fussilat; 41:31. Ìdí ni pé, gbígba ẹ̀san lára alábòsí tàbí gbígba ààrọ̀ kò sọ pé mùsùlùmí kò ní ẹ̀mí àforíjìn, àmọ́ ó lè má nìí agbára láti ṣàmójú kúrò fún alábòsí náà. Bí àpẹẹrẹ, kí ẹnì kan ba dúkìá mùsùlùmí jẹ́, yálà ó ṣèèsì tàbí ó mọ̀ọ́mọ̀, mùsùlùmí lè gbẹ̀san ààrọ̀ níwọ̀n ìgbà tí agbára rẹ̀ kò bá gbé àtúnṣe rẹ̀ tàbí ìràpadà rẹ̀. Kò sì níí gbà ju ohun tí wọ́n bàjẹ́ lọ. Àti pé tí kò bá sí òfin ẹ̀san gbígbà rárá, àwọn ènìyàn kò níí yé máa fi ìnira àti aburú kan àwọn ẹlòmíìràn. Nítorí náà, ẹ̀san gbígbà tàbí ààrọ̀ gbígbà kò sọ mùsùlùmí di ẹni tí kò lẹ́mìí àforíjìn gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe lérò láti fi ba àwa mùsùlùmí lórúkọ jẹ́.


الصفحة التالية
Icon