Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),1 ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām). 2
____________________
1. Āyah yìí ń fi kókó pàtàkì kan rinlẹ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí ayé Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé, ṣíwájú kí ìmísí mímọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀kalẹ̀ fún un kò sí nínú ẹni t’ó nímọ̀ sí tírà sánmọ̀ kan kan, kò sì dá ìgbàgbọ́ òdodo mọ. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún fi èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah ad-Duhā; 93: 7. Àmọ́ níkété tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bẹ̀rẹ̀ sí gba ìmísí mímọ́, Allāhu fi ìmọ̀ tírà al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ ọ́n. Ó sì di olùpèpè sínú ìmọ̀nà. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ni ìṣẹ̀mí ayé wọn rí bí Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti ṣe rí àfi ẹni tí bàbá rẹ̀ bá jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Àmọ́ ṣá, kò sí abọ̀rìṣà kan tí Allāhu sọ di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rí. Ẹni tí Allāhu máa sọ di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ lè má tí ì mọ tírà nígbà tí Ọlọ́hun kò ì tí ì fún un, ó sì lè má tí ì dá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀, nígbà tí Ọlọ́hun kò tí ì ròyìn Ara Rẹ̀ fún un, àmọ́ kò níí sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ tàbí àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ènìyàn. Kódà, láti kékeré wọn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti máa ń jogún òye fún wọn pé, “irọ́ lòrìṣà” títí àsìkò ìmísí wọn yóò fi dé.
Síwájú sí i, tí ẹnì kan bá sì sọ pé, iṣẹ́ wiridi ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń ṣe nínú ọ̀gbun Hirā ṣíwájú kí ó tó di Ànábì Ọlọ́hun, irọ́ l’ó fi pa. Ìdí ni pé, ẹnì kan kì í ṣe wiridi láì gbọwọ́, ta ni ó fún Ànábì lọ́wọ́ wiridi? Kò sí. Bákan náà, kò sí ojú ọ̀nà wiridi tí kò lórúkọ, kí ni orúkọ tọrikọ sūfī tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ṣe? Kò sí. Èyí t’ó wá kó ọ̀rọ̀ tán nílẹ̀ ni pé, títẹ̀lé Muhammad ọmọ ‘Abdullah (sollalāhu 'alayhi wa sallam), kò di ẹ̀sìn àfi láti àsìkò tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì lọ sínú ọ̀gbun Hirā mọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mọlāika Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fún ní ìmísí àkọ́kọ́. Nítorí náà, Ànábì kì í ṣe sūfī, kò sì ṣe wiridi sūfī rí. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọsọs; 28:56.


الصفحة التالية
Icon