Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ ṣeyèméjì nípa rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
____________________
Àgbọ́yé mẹ́ta ni àwọn tafsīr mú wá lórí àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ t’ó jẹyọ nínú “ wa’innahu”. Àgbọ́yé kìíní ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún “Ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ àmì láti mọ̀ pé dájúdájú Àkókò náà ti súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Àgbọ́yé kejì ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ìsọ̀kalẹ̀ al-Ƙur̂ān, tí ó ń fi ìmọ̀ mọ̀ wá, tí ó sì ń fi àmì hàn wá nípa ìsúnmọ́ Àkókò náà. Àgbọ́yé kẹta ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ìwásáyé Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo rẹ̀ túmọ̀ sí pé, ìkọ̀ọ̀kan wọn ń jẹ́ àmì ńlá láti mọ̀ pé Àkókò náà ti fẹ́ ṣẹlẹ̀. Àgbọ́yé mẹ́tààta wọ̀nyí kúkú ni òdodo ọ̀rọ̀ nítorí pé, kò sí èyí tí kò ní ẹ̀rí aṣèrànwọ́ láti inú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Kò sì sí ọ̀kan nínú àwọn àgbọ́yé mẹ́tààta wọ̀nyí tí ẹ̀rí àtakò wà fún láti inú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ nígbà tí pọ́nna bá jẹyọ nínú āyah al-Ƙur’ān bí irú èyí, ọ̀nà kan pàtàkì nínú ìyọní-pọ́nna ni lílo hadīth Ànábì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí á tó lè lo hadīth kan kan fún ìyọní-pọ́nna, al-Ƙur’ān fúnra rẹ̀ ni ohun àkọ́kọ́ tí a máa lò. Èyí máa ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ wíwo sàkánì tí ọ̀rọ̀ onípọ́nna náà ti jẹyọ. A máa wòye sí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá á bọ̀ níwájú àti ọ̀rọ̀ tí ó tún mú wá lẹ́yìn rẹ̀. Kódà ìwòye yìí lè ṣẹlẹ̀ nígbà mìíràn nínú āyah kan náà tàbí nínú sūrah mìíràn pẹ̀lú. Nítorí náà, àgbọ́yé t’ó ń fi rinlẹ̀ pé ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ ni āyah náà ń sọ nípa rẹ̀ l’ó padà gbéwọ̀n jùlọ nítorí pé, ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó ń sọ bọ̀ láti inú āyah 57 títí dé āyah 65. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa al-Ƙur’ān tàbí ọ̀rọ̀ nípa Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ sá, tí ẹnì kan bá bá àgbọ́yé mìíràn lọ nínú àwọn àgbọ́yé méjèèjì yòókù, kò la àtakò lọ níwọ̀n ìgbà tí onítọ̀un kò bá ti tako ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ lópin ayé nítorí pé, níwọ̀n ìgbà tí hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ti fi rinlẹ̀, aláìgbàgbọ́ tí ó máa jẹ̀bi ikú lábẹ́ òfin ’Islām ni ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí t’ó bá takò ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ lópin ayé.


الصفحة التالية
Icon