Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n.
____________________
Àpẹẹrẹ àwọn olùṣìnà jùlọ yìí ni àwọn kristiẹni tí wọ́n ń pe Jésù Kristi pẹ̀lú àwáwí pé ó wà láàyè nínú sánmọ̀, àmọ́ tí wọn kò mọ̀ pé ó kàn wà nínú sánmọ̀ ni, kò lè gbọ́ ìpè wọn áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa jẹ́pè wọn. Allāhu nìkan ṣoṣo l’Ó lè jẹ́pè àwọn ẹrúsìn rẹ̀, onígbàgbọ́ òdodo.


الصفحة التالية
Icon