Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni (al-Ƙur’ān) ti wá, tí ẹ sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ẹlẹ́rìí kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì jẹ́rìí lórí irú rẹ̀, tí ó sì gbà á gbọ́, (àmọ́) tí ẹ̀yin ṣègbéraga sí i, (ṣé ẹ ò ti ṣàbòsí báyẹn bí?). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.


الصفحة التالية
Icon